Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 3:15-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Sólómónì jí: ó sì mọ̀ pé àlá ni.Ó sì padà sí Jérúsálẹ́mù, ó sì dúró níwájú àpótí májẹ̀mú Olúwa, ó sì rúbọ ọrẹ sísun àti ẹbọ àlàáfíà. Nígbà náà ni ó ṣe àṣè fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ.

16. Lẹ́yìn náà ni àwọn obìnrin alágbérè méjì wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì dúró níwájú rẹ.

17. Ọ̀kan nínú wọn sì wí pé, “Olúwa mi, èmi àti obìnrin yìí ń gbé nínú ilé kan. Èmi sì bí ọmọ ní ilé pẹ̀lú rẹ̀.

18. Ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn ìgbà tí mo bímọ tan, obìnrin yìí sì bímọ pẹ̀lú. A sì nìkan dá wà; kò sí ẹlòmíràn ní ilé bí kò ṣe àwa méjèèjì nìkan.

19. “Ní òru, ọmọ obìnrin yìí kú nítorí tí ó sùn lé e.

20. Nígbà náà ni ó sì dìde ní ọ̀gànjọ́, ó sì gbé ọmọ tèmi lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi nígbà tí èmi ìránṣẹ́ rẹ ti sùn lọ. Ó sì tẹ́ ẹ sí àyà rẹ̀, ó sì tẹ́ òkú ọmọ tirẹ̀ sí àyà mi.

21. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì mo sì dìde láti fi ọmú fún ọmọ mi: ó sì ti kú! Ṣùgbọ́n nígbà tí mo sì wò ó fín ní òwúrọ̀, mo sì ríi pé kì í ṣe ọmọ mi tí mo bí.”

22. Obìnrin kejì sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Èyí alààyè ni ọmọ mi, èyí òkú ni ọmọ tirẹ̀.” Èyí òkú ni tirẹ̀; èyí alààyè ni tèmi.Ṣùgbọ́n èyí àkọ́kọ́ tún wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Èyí òkú ni tìrẹ; èyí alààyè ni tèmi.” Báyìí ni wọ́n sì ń jiyàn níwájú ọba.

23. Ọba sì wí pé, “Ẹni yìí wí pé, ‘Ọmọ mi ni ó wà láàyè, ọmọ tirẹ̀ ni ó kú,’ nígbà tí ẹni èkejì náà ń wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́! Ọmọ tirẹ̀ ni ó kú, ọmọ tèmi ni ó wà láàyè.’ ”

24. Nígbà náà ni ọba wí pé, “Ẹ mú idà fún mi wá.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú idà wá fún ọba.

25. Ọba sì pàṣẹ pé: “Ẹ gé alààyè ọmọ sí méjì, kí ẹ sì mú ìdajì fún ọ̀kan, àti ìdajì fún èkejì.”

26. Obìnrin tí ọmọ tirẹ̀ wà láàyè sì kún fún àánú fún ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, Olúwa mi, ẹ fún un ní alààyè ọmọ! Ẹ má ṣe pa á!”Ṣùgbọ́n obìnrin èkejì sì wí pé, “Kì yóò jẹ́ tèmi tàbí tìrẹ̀. Ẹ gé e sí méjì!”

27. Nígbà náà ni ọba dáhùn, ó wí pé, “Ẹ fi alààyè ọmọ fún obìnrin àkọ́kọ́. Ẹ má ṣe pa á: òun ni ìyá rẹ̀.”

28. Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì gbọ́ ìdájọ́ tí ọba ṣe, wọ́n sì bẹ̀rù níwájú ọba, nítorí wọ́n ti rí í pé ó ní ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti ṣe ìdájọ́.

Ka pipe ipin 1 Ọba 3