Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 22:7-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ṣùgbọ́n Jèhóṣáfátì béèrè pé, “Ǹjẹ́ wòlíì Olúwa kan kò sí níhìn ín, tí àwa ìbá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?”

8. Ọba Ísírẹ́lì dá Jèhóṣáfátì lóhùn pé, “Ọkùnrin kan sì wà, lọ́dọ̀ ẹni tí àwa lè béèrè lọ́wọ́ Olúwa, ṣùgbọ́n mo kórìíra rẹ̀ nítorí kì í sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere kan nípa mi, bí kò ṣe ibi. Míkáyà ọmọ Ímílà ni.”Jéhósáfátì sì wí pé, “Kí ọba má ṣe sọ bẹ́ẹ̀.”

9. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì sì pe ìránṣẹ́ kan, ó sì wí pé, “Lọ yára mú Míkáyà, ọmọ Ímílà wá.”

10. Ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì ọba Júdà jókòó lórí ìtẹ́ wọn, wọ́n wọ aṣọ ìgúnwà wọn ní ìta ẹnubodè Samáríà, gbogbo àwọn wòlíì náà sì ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn.

11. Ṣedekíà ọmọ Kénáánà sì ṣe ìwo irin fún ara rẹ̀, ó sì wí pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Wọ̀nyí ni ìwọ yóò fi kan àwọn ará Árámù títí ìwọ yóò fi run wọ́n.’ ”

12. Gbogbo àwọn wòlíì tó kù sì ń sọtẹ́lẹ̀ ohun kan náà wí pé, “Kọlu Ramoti-Gílíádì, kí o sì ṣẹ́gun.” Wọ́n sì wí pé, “nítorí tí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”

13. Ìránṣẹ́ tí ó lọ pe Míkáyà wí fún un pé, “Wò ó, ẹnu kan náà ni ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì fi jẹ́ rere fún ọba. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ bá ti àwọn tókù mu, kí o sì sọ rere.”

14. Ṣùgbọ́n Míkáyà wí pé, “Bí Olúwa ti wà, ohun tí Olúwa bá sọ fún mi ni èmi yóò sọ fún un.”

Ka pipe ipin 1 Ọba 22