Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 2:2-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ó sì wí pé, “Èmi ti fẹ́ lọ sí ọ̀nà gbogbo ayé, nítorí náà jẹ́ alágbára kí o sì fi ara rẹ hàn bí ọkùnrin,

3. kí o sì wòye ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ béèrè, rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí o sì pa àṣẹ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti ìdájọ́ rẹ, àti ẹ̀rí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé òfin Mósè, nítorí kí ìwọ kí ó le è máa ṣe rere ní ohun gbogbo tí ìwọ ṣe, àti ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ,

4. kí Olúwa kí ó lè pa ìlérí rẹ̀ tí ó sọ nípa tèmi mọ́ pé: ‘Bí àwọn ọmọ rẹ bá kíyèsí ọ̀nà wọn, tí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà wọn àti ọkàn wọn rìn níwájú mi ní òtítọ́, o kì yóò sì kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.’

5. “Ìwọ pẹ̀lú sì mọ ohun tí Jóábù ọmọ Ṣérúyà ṣe sí mi àti ohun tí ó ṣe sí balógun méjì nínú àwọn ológun Ísírẹ́lì, sí Ábínérì ọmọ Nérì àti sí Ámásà ọmọ Jétérì. Ó sì pa wọ́n, ó sì ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ ní ìgbà àlàáfíà bí í ti ojú ogun ó sì fi ẹ̀jẹ̀ náà sí ara àmùrè rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àti sí ara Sálúbàtà rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹṣẹ̀ rẹ̀.

6. Ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n rẹ̀, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà-òkú ní àlàáfíà.

7. “Ṣùgbọ́n fi inú rere hàn sí àwọn ọmọ Bárísíláì, ti Gílíádì, jẹ́ kí wọn wà lára àwọn tí ó ń jẹun lórí tábìlì rẹ̀. Wọ́n dúró tì mí nígbà tí mo sá kúrò níwájú Ábúsálómù arákùnrin rẹ̀.

8. “Àti kí o rántí, Ṣíméhì ọmọ Gérà ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì tí Báhúrímù wà pẹ̀lú rẹ̀, tí ó bú mi ní èébú tí ó korò ní ọjọ́ tí mo lọ sí Máhánáímù. Nígbà tí ó sọ̀kalẹ̀ wá pàdé mi ní Jọ́dánì, mo fi Olúwa búra fún un pé: ‘Èmi kì yóò fi idà pa ọ́.’

9. Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí, má ṣe kíyèsí í gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin ọlọ́gbọ́n ni ìwọ ṣe; ìwọ yóò mọ ohun tí ìwọ yóò ṣe sí i. Mú ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sínú isà-òkú pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.”

10. Nígbà náà ni Dáfídì sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dáfídì.

Ka pipe ipin 1 Ọba 2