“Ìwọ pẹ̀lú sì mọ ohun tí Jóábù ọmọ Ṣérúyà ṣe sí mi àti ohun tí ó ṣe sí balógun méjì nínú àwọn ológun Ísírẹ́lì, sí Ábínérì ọmọ Nérì àti sí Ámásà ọmọ Jétérì. Ó sì pa wọ́n, ó sì ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ ní ìgbà àlàáfíà bí í ti ojú ogun ó sì fi ẹ̀jẹ̀ náà sí ara àmùrè rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àti sí ara Sálúbàtà rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹṣẹ̀ rẹ̀.