Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 17:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èlíjà ará Tíṣíbì, láti Tíṣíbì ní Gílíádì wí fún Áhábù pé, “Bí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti wà, ẹni tí èmi ń sìn, kì yóò sí ìrì tàbí òjò ní ọdún díẹ̀ tí ń bọ̀ bí kò ṣe nípa ọ̀rọ̀ mi.”

2. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Èlíjà wá pé:

3. “kúrò níhìn ín, kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, kí o sì fi ara rẹ pamọ́ níbi odò Kérítì, tí ń bẹ níwájú Jọ́dánì.

4. Ìwọ yóò mu nínú odò náà, mo sì ti pàṣẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò láti máa bọ́ ọ níbẹ̀.”

5. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún un. Ó sì lọ sí ẹ̀bá odò Kérítì, tí ń bẹ níwájú Jọ́dánì, ó sì dúró síbẹ̀.

6. Àwọn ẹyẹ ìwò sì mú àkàrà àti ẹran wá fún un ní òwúrọ̀, àti àkàrà àti ẹran ní alẹ́, ó sì ń mu nínú odò náà.

7. Ó sì ṣe lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, odò náà sì gbẹ nítorí kò sí òjò ní ilẹ̀ náà.

8. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ ọ́ wá wí pé:

9. “Lọ nísinsìn yìí sí Ṣáréfátì ti Ṣídónì, kí o sì dúró síbẹ̀. Èmi ti pàṣẹ fún obìnrin opó kan níbẹ̀ láti máa bọ́ ọ.”

10. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sí Ṣáréfátì. Nígbà tí ó sì dé ibodè ìlú náà, obìnrin opó kan ń ṣa igi jọ níbẹ̀. Ó sì ké sí i, ó sì béèrè pé, “Ǹjẹ́ o lè bu omi díẹ̀ fún mi wá nínú ohun èlò kí èmi kí ó lè mu?”

11. Bí ó sì ti ń lọ bù ú wá, ó ké sí i pé, “Jọ̀ ọ́, mú òkèlè oúnjẹ díẹ̀ fún mi wá lọ́wọ́ rẹ.”

12. Obìnrin opó náà sì dá a lóhùn wí pé, “Bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti wà, èmi kò ní àkàrà: bí kò ṣe ìkúnwọ́ ìyẹ̀fun nínú ìkòkò àti òróró díẹ̀ nínú kólòbó. Èmi ń ṣa igi díẹ̀ jọ láti kó lọ ilé, kí èmi kí ó sì pèsè rẹ̀ fún mi àti fún ọmọ mi, kí àwa lè jẹ ẹ́: kí a sì kú.”

13. Èlíjà sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Lọ, kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti wí. Ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ṣe àkàrà kékeré kan fún mi nínú rẹ̀ ná, kí o sì mú fún mi wá, lẹ́yìn náà, kí o ṣe tìrẹ àti ti ọmọ rẹ.

14. Nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Ìkòkò ìyẹ̀fun náà kì yóò ṣófo, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró náà kì yóò gbẹ, títí di ọjọ́ tí Olúwa yóò rọ òjò sí orí ilẹ̀.’ ”

Ka pipe ipin 1 Ọba 17