Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 11:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Sólómónì ọba fẹ́ ọ̀pọ̀ àjèjì obìnrin yàtọ̀ sí ọmọbìnrin Fáráò, àwọn ọmọbìnrin Móábù, àti ti Ámónì, ti Édómù, ti Sídónì àti ti àwọn ọmọ Hítì.

2. Wọ́n wá láti orílẹ̀ èdè tí Olúwa ti wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fẹ́ wọn níyàwó tàbí ní ọkọ, nítorí wọn yóò yí ọkàn yín padà sí òrìṣà wọn.” Síbẹ̀ síbẹ̀ Sólómónì fà mọ́ wọn ní ìfẹ́.

3. Ó sì ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) obìnrin, àwọn ọmọ ọba àti ọ̀ọ́dúnrun (300) àlè, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà.

4. Bí Sólómónì sì ti di arúgbó, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà sí ọlọ́run mìíràn, ọkàn rẹ̀ kò sì ṣe déédé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn Dáfídì bàbá rẹ̀ ti ṣe.

5. Ó tọ Ásítórétì òrìṣà àwọn ará Sídónì lẹ́yìn, àti Mílíkómì òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ámónì.

6. Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì ṣe búburú níwájú Olúwa; kò sì tọ Olúwa lẹ́yìn ní pípé, bí Dáfídì bàbá rẹ̀ ti ṣe.

7. Lórí òkè tí ń bẹ níwájú Jérúsálẹ́mù, Sólómónì kọ́ ibi gíga kan fún Kémósì, òrìṣà ìríra Móábù, àti fún Mólékì, òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ámónì.

8. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún gbogbo àwọn àjèjì obìnrin rẹ̀, ẹni tí ń sun tùràrí, tí wọ́n sì ń rúbọ fún òrìṣà wọn.

9. Olúwa bínú sí Sólómónì nítorí ọkàn rẹ̀ ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó ti fi ara hàn án lẹ́ẹ̀méjì.

10. Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti kìlọ̀ fún Sólómónì kí ó má ṣe tọ àwọn Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn, ṣùgbọ́n Sólómónì kò pa àṣẹ Olúwa mọ́.

Ka pipe ipin 1 Ọba 11