Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 10:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ayaba Ṣébà gbọ́ òkìkí Sólómónì àti ìbáṣepọ̀ rẹ̀ níti orúkọ Olúwa, ó sì wá láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè líle.

2. Ó sì wá sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹgbẹ́ èrò ńlá ńlá, pẹ̀lú ràkúnmí tí ó ru tùràrí, ati ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti òkúta iyebíye, ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Sólómónì, ó sì bá a sọ gbogbo èyí tí ń bẹ ní ọkàn rẹ̀.

3. Sólómónì sì dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyí tí ó ṣòro fún ọba láti ṣàlàyé fún un.

4. Nígbà tí ayaba Ṣébà sì rí gbogbo ọgbọ́n Sólómónì àti ààfin tí ó ti kọ́.

5. Oúnjẹ tí ó wà lórí i tábìlì rẹ̀, ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti ìdúró àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ìwọṣọ wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀, àti ẹbọ ọrẹ̀ sísun tí ó sun ní ilé Olúwa, kò sì sí ẹ̀mí kan nínú rẹ̀ mọ́!

6. Ó sì wí fún ọba pé, “Òtítọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní orílẹ̀ èdè mi níti iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ.

7. Ṣùgbọ́n èmi kò sì gba nǹkan wọ̀nyí gbọ́ títí ìgbà tí mo wá, tí mo sì fi ojú ara mi rí i. Sì kíyèsí i, a kò sọ ìdajì wọn fún mi; ìwọ sì ti fi ọgbọ́n àti ìrora kọjá òkìkí tí mo gbọ́.

8. Báwo ni inú àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe dùn tó! Báwo ni inú dídùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n sì ń gbọ́ ọgbọ́n rẹ!

9. Ìbùkún ni fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó ní inú dídùn sí ọ, tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ Ísírẹ́lì. Nítorí tí Olúwa fẹ́ràn Ísírẹ́lì títí láé, ni ó ṣe fi ọ́ jọba, láti ṣe ìdájọ́ àti òdodo.”

Ka pipe ipin 1 Ọba 10