Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 29:16-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Olúwa Ọlọ́run wa tí fi gbogbo pípọ̀ yìí tí àwa ti pèṣè fún kíkọ́ ilé Olúwa fun orúkọ, mímọ́ Rẹ̀, ó wá láti ọwọ́ ọ̀ rẹ, gbogbo Rẹ̀ sì jẹ́ tirẹ̀.

17. Èmi mọ̀ Ọlọ́run mi, wí pé ìwọ̀ dán ọkàn wò, ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn pẹ̀lú òtítọ́ inú. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́ pẹ̀lú òtítọ́. Nísinsìn yìí èmi ti ríi pẹ̀lú ayọ̀ bí àwọn ènìyàn yìí tí ó wà níbí ti fi fún ọ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́.

18. Olúwa Ọlọ́run àwọn baba a wa Ábúráhámù, Ísákì àti Ísírẹ́lì pa ìfẹ́ yìí mọ́ ninú ọkàn àwọn ènìyàn rẹ títí láé pẹ̀lú pípa ọkàn mọ́ lóòtọ́ sí ọ.

19. Àti fún ọmọ mi Sólómónì ní ìfọkànsìn tòótọ́ láti pa àṣẹ rẹ mọ́ àwọn ohun tí ó nílò àti òfin àti láti ṣe ohun gbogbo láti kọ́ ààfin bí ti ọba fún èyí tí mo ti pèsè.”

20. Dáfídì sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn pé, Nísinsìn yìí, ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín. Gbogbo ènìyàn sì fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì tẹ orí wọn ba, wọ́n wólẹ̀ fún Olúwa àti ọba.

21. Ni ọjọ́ kejì, wọ́n rú ẹbọ sí Olúwa, wọ́n sì rú ẹbọ ọrẹ ṣíṣun sí i: ẹgbẹ̀rún kan akọ màlúù, ẹgbẹ̀rin kan àgbò, àti ẹgbẹ̀rin kan akọ ọ̀dọ́ àgùntàn. Lápapọ̀ pẹ̀lú ọrẹ mímu àti àwọn ẹbọ mìíràn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún gbogbo Ísírẹ́lì.

22. Wọ́n jẹ wọ́n sì mu pẹ̀lú ayọ̀ kíkún ní iwájú Olúwa ní ọjọ́ náà.Nígbà náà wọ́n yan Sólómonì ọmọ Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba lẹ́ẹ̀kejì wọ́n fi àmì òróró yàn án níwájú Olúwa láti ṣe olórí àti Ṣádókù láti ṣe àlùfáà.

23. Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì jókòó lórí ìtẹ́ Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọba ní ipò bàbá a Rẹ̀ Dáfídì. O ṣe àṣeyọrí, gbogbo Ísírẹ́lì sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu.

24. Gbogbo àwọn ìjòyè àti àwọn ọkùnrin alágbára, pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọba Dáfídì tẹrí ara wọn ba fún ọba Sólómónì.

25. Olúwa gbé Solómónì ga púpọ̀ ní ojú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì kẹ́ ẹ ní ìkẹ́ ọlá ńlá, ní irú èyí tí a kò kẹ́ ọba kankan ṣáájú Rẹ̀ tí ó jẹ lórí Ísírẹ́lì.

26. Dáfídì ọmọ Jéṣè jẹ́ ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.

27. Ó jọba lórí Ísírẹ́lì fún ogójì ọdún; ọdún méje ni ó jọba ní Hẹ́súrónì, ó sì jọba ní ọdún mẹ́talélọ́gbọ̀n (33) ní Jérúsálẹ́mù.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 29