1 Kíróníkà 29:20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
Dáfídì sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn pé, Nísinsìn yìí, ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín. Gbogbo ènìyàn sì fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì tẹ orí wọn ba, wọ́n wólẹ̀ fún Olúwa àti ọba.