Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 28:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Dáfídì pe gbogbo àwọn oniṣẹ́ ti Ísírẹ́lì láti pẹ́jọ ní Jérúsálẹ́mù: Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà, àwọn alákòóṣo ìpín nínú iṣẹ́ bí ọba, àwọn alákòóṣo ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóṣo ọrọrún àti àwọn onísẹ́ tí ó wà ní ìdí bíbojútó gbogbo àwọn ẹrù àti ohun ọ̀sìn tí ó jẹ́ ti ọba àti àwọn ọmọ Rẹ̀ pẹ̀lú ààfin àwọn onísẹ́ ààfin, àwọn ọkùnrin alágbára àti gbogbo àwọn ògbójú jagunjagun lápapọ̀.

2. Ọba Dáfídì dìde dúró ní ẹṣẹ̀ Rẹ̀, o sì wí pé Fetísílẹ̀ sí mi, ẹyin ará mi àti ẹ̀yin ènìyàn mi. Èmi ní o ni ọkàn mi láti kọ́ ilé gẹ́gẹ́ bí ibi ìsinmi fún àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú tí Olúwa fún àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run wa, èmi sì gbèrò láti kọ́ ọ.

3. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún mi pé: Ìwọ kò gbodò kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí ìwọ jẹ́ jagunjagun, ìwọ sì ti tàjẹ̀sílẹ̀.

4. “Síbẹ̀ Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì yàn mí láti gbogbo ìdílé láti jẹ́ ọba lórí Ísírẹ́lì, títí láé. Ó yan Júdà gẹ́gẹ́ bí olórí, àti láti ilé Júdà, ó yan ìdílé mi, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ baba à mí, ó tẹ́ Ẹ lọ́rùn láti fi mí ṣe ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.

5. Ninú gbogbo àwọn ọmọ mi pẹ̀lú Olúwa ti fún mi ní púpọ̀, ó ti yan ọmọ mi Sólómónì láti jòkó lórí ìtẹ́ ìjọba ti Olúwa lóri Isírẹ́lì.

6. Ó wí fún mi pé, Sólómónì ọmọ rẹ ni ẹni tí yóò kọ́ ilé mi àti àwọn ààfin mi, Nítorí tí èmi ti yàn án láti ṣe ọmọ mi èmi yóò sì jẹ́ baba a Rẹ̀.

7. Èmi yóò fi ìdí ìjọba Rẹ̀ kalẹ̀ títí láé tí kò bá kọ̀ láti gbé àṣẹ àti òfin mi jáde, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe é ní àsìkò yìí.

8. “Bẹ́ẹ̀ ni, nísinsìn yìí, èmi pàṣẹ fún ọ ní ojú gbogbo Ísírẹ́lì àti ní ti ìpéjọpọ̀ tí Olúwa, àti ní etí ìgbọ́ Ọlọ́run wa: Ṣọ́ra kó o sì tẹ̀lé gbogbo òfin Olúwa Ọlọ́run rẹ kí ìwọ kí ó le jogún ilẹ̀ dáradára yìí, kí o sì mú un lọ síwájú gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ fún àwọn ìran ọmọ rẹ títí láé.

9. “Àti ìwọ, ọmọ mi Sólómónì, rántí Ọlọ́run baba à rẹ, kí o sì sìn-ín pẹ̀lú tọkàntọkàn pẹ̀lú ìfọkànsí pẹ̀lú ọkàn tí ó pé, nítorí Olúwa ṣàwárí gbogbo ọkàn ó sì mọ gbogbo èrò. Tí ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i; ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ọ́ sílẹ̀, òun yóò kọ̀ọ́ títí láé.

10. Gbèrò báyìí nítorí tí Olúwa ti yàn ọ́ láti kọ́ ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí ilé tí a yà sí mímọ́ fún Olúwa. Jẹ́ alágbára kí ó sì ṣe iṣẹ́ náà.”

11. Nígbà náà, Dáfídì fún Sólómónì ọmọ Rẹ̀ ní ètò fún èbúté ilé Olúwa náà, kíkọ́ ọ Rẹ̀, àwọn yàrá ìṣúra Rẹ̀, ibi òkè Rẹ̀, àwọn ìyẹ̀wù Rẹ̀ àti ibi ìpètù sí Rẹ̀.

12. Ó fún un ní àwọn ètò gbogbo èyí tí ẹ̀mí ti fi sí ọkàn Rẹ̀ fún ti ààfin ilé Olúwa àti gbogbo yàrá tí ó yíká fún ìṣúra ilé Ọlọ́run àti fún ìṣúra fún ohun yíyà sọ́tọ̀.

13. Ó fún un ní àwọn ìlànà fún ìpín ti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì àti fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa àti fún gbogbo ohun èlò tí wọn ó lò nínú ìsìn Rẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 28