Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 22:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà Dáfídì wí pé, “Ilé Olúwa Ọlọ́run ni ó gbọdọ̀ wà níbí, àti pẹ̀lú pẹpẹ ọrẹ síṣun fún Ísírẹ́lì.”

2. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì paláṣẹ láti kó àwọn àlejò tí ń gbé ní Ísírẹ́lì jọ, àti wí pé lára wọn ni ó ti yan àwọn agbé-òkúta láti gbé òkúta dáradára láti fi kọ́lé Ọlọ́run.

3. Ó sì pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye irin láti fi ṣe ìṣọ́ fún àwọn ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà àti fún idẹ; àti fún òpó idẹ ni àìní ìwọ̀n.

4. Ó sì tún pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi Kédárì tí ó jẹ́ àìníye, nítorí pé àwọn ará Ṣídónì àti àwọn ará Tírè mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kédárì wá fún Dáfídì.

5. Dáfídì wí pé, Ọmọ mi Sólómónì ọ̀dọ́mọdé ni ó sì jẹ́ aláìní ìríri, ilé tí a ó kọ́ fún Olúwa gbọdọ̀ jẹ́ títóbi jọjọ, kí ó sì ní òkìkí àti ògo jákèjádò gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè. Nítorí náà ni èmi yóò ṣe pèsè sílẹ̀ fún un. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sì ṣe ìpèsè sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ kí ó tó di wí pé ó kú.

6. Nígbà náà ó pe Sólómónì ọmọ Rẹ̀ ó sì sọ fun pé kí ó kọ́ ilé fún-un Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

7. Dáfídì sì wí fún Sólómónì pé, “Ọmọ mi, mo sì ní-in ní ọkàn mi láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi.

8. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: ‘Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, o sì ti ja ọ̀pọ̀ ogun ńlá ńlá, kì í ṣe ìwọ ni yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ lórí ilẹ̀ ní ojú mi.

9. Ṣùgbọ́n ìwọ yóò ní ọmọ tí yóò sì jẹ́ ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ àti onísinmi, Èmi yóò sì fún-un ní ìsinmi láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ọ̀ta Rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ yíká. Orúkọ Rẹ̀ yóò sì máa jẹ́ Sólómónì, Èmi yóò sì fi àlàáfíà àti ìdákẹ́jẹ́ fún Ísírẹ́lì lásìkò ìjọba Rẹ̀.

10. Òun ni ẹni náà tí yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi. Yóò sì jẹ́ ọmọ mi, èmi yóò sì jẹ́ baba Rẹ̀ èmi yóò sì fi ìdi ìtẹ́ ìjọba Rẹ̀ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì láéláé.’

11. “Nísinsìn yìí, ọmọ mi, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, kí ìwọ kí ó sì ní àṣeyọrí kí o sì kọ́ ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 22