Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 19:12-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Jóábù wí pé Tí àwọn ará Ṣíríà bá le jù fún mi, nígbà náà, ìwọ ni kí o gbà mí; Ṣùgbọ́n tí àwọn ará Ámónì bá le jù fún ọ, Nígbà náà èmi yóò gbà ọ́.

13. Jẹ́ alágbára kí ẹ sì jẹ́ kí a jà pẹ̀lú ìgboyà fún àwọn ènìyàn wa àti àwọn ìlú ńlá ti Ọlọ́run wa. Olúwa yóò ṣe ohun tí ó dára ní ojú Rẹ̀.

14. Nígbà náà Jóábù àti àwọn ọmọ ogun pẹ̀lú Rẹ̀ lọṣíwájú láti lọ jà pẹ̀lú àwọn ará Ṣíríà. Wọ́n sì sálọ kúrò níwájú Rẹ̀.

15. Nígbà ti àwọn ará Ámónì ri pé àwọn ará Ṣíríà ń sálọ, àwọn náà sálọ kúrò níwájú arákùnrin Rẹ̀ Ábíṣáì. Wọ́n sì wọ inú ìlú ńlá lọ. Bẹ́ẹ̀ ni Jóábù padà lọ sí Jérúsálẹ́mù.

16. Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ará Ṣíríà rí wí pé àwọn Ísírẹ́lì ti lé wọn, wọ́n rán ìránṣẹ́. A sì mú àwọn ará Ṣíríà rékọjá odò wá, pẹ̀lú Ṣófákì alákóso ọmọ ogun Hádádésérì, tí ó ń darí wọn.

17. Nígbà tí a sọ fún Dáfídì nípa èyí, ó pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ wọ́n sì rékọjá Jódánì; Ó lọ ṣíwájú wọn, ó sì fa ìlà ogun dojúkọ wọ́n. Dáfídì fa ìlà Rẹ̀ láti bá àwọn ará Ṣíríà jagun wọ́n sì doju ìjà kọ ọ́.

18. Ṣùgbọ́n wọ́n sálọ kúrò níwájú Ísírẹ́lì, Dáfídì sì pa ẹgbẹ̀rún méje agun-kẹ̀kẹ́ wọn àti ẹgbàá mẹ́rin ọmọ-ogun ẹlẹ́sẹ̀. Ó pa Ṣófákì alákóṣo ọmọ ogun wọn pẹ̀lú.

19. Nígbà tí àwọn ẹrú Hádádé-ṣérì ríi wí pé Ísírẹ́lì ti borí wọn, wọ́n ṣe àlàáfíà pẹ̀lú Dáfídì, wọ́n sì ń sìn ní abẹ́ ẹ Rẹ̀.Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ará Ṣíríà kò ní ìfẹ́ sí ríran àwọn ará Ámónì lọ́wọ́ mọ́.

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 19