Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 17:5-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Èmi kò tí ì gbé nínú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú Isírẹ́lì jáde wá láti Éjíbítì títí di òní yìí. Èmi ń lọ láti àgọ́ dé àgọ́ àti láti ibùgbé dé ibùgbé.

6. Ni ibi gbogbo tí mo ti bá gbogbo Isírẹ́lì rìn dé, ǹjẹ́ mo wí nǹkankan sí ọ̀kan nínú àwọn adarí Ísírẹ́lì, tí èmí pàṣẹ́ fún láti máa jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn mi, wí pé, “Kí ní ṣe tí ẹ̀yín kò fi kọ́ ilé tí a fi igi kédárì kọ́ fún mi?” ’

7. “Nígbà náà, sọ fún ìránṣẹ́ mi Dáfídì pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa alágbára wí: Èmi mú un yín láti pápá oko tútù wá, àní kúrò lẹ́yìn agbo àgùntàn, kí ìwọ lè máa ṣe olórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.

8. Èmi ti wà pẹ̀lú yín ní, ibi kíbi tí ẹ̀yin ti ń lọ, ẹ̀mi sì ti gé gbogbo àwọn ọ̀ta yín kúrò níwáju yín. Nísinsin yìí Èmi yóò mú kí orúkọ rẹ kí ó dàbí orukọ àwọn ènìyàn ńlá jùlọ̀ tí ó wà ní ayé.

9. Èmi yóò sì pèṣè àyè kan fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, kí wọn kí ó lè ní ilé ti wọn kí a má sì se dàmú wọn mọ́. Àwọn ènìyàn búburú kì yóò ni wọ́n lára mọ́, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti se ní ìbẹ̀rẹ̀.

10. Bí wọ́n sì ti ṣe láti ìgbà tí mo ti yan àwọn aṣájú lórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì. Èmi pẹ̀lú yóò sẹ́gun gbogbo àwọn ọ̀ta yín.“ ‘Èmi sọ fún yín pé Olúwa yóò kọ́ ilé kan fún yín:

11. Nígbà ti ọjọ́ rẹ bá kọjá, tí ìwọ bá lọ láti lọ bá àwọn baba à rẹ, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ sókè láti rọ́pò rẹ, ọ̀kan lára àwọn ọmọ tìrẹ, Èmi yóò sì fìdí ìjọba Rẹ̀ kalẹ̀.

12. Òun ni ẹni tí yóò kọ́ ilé fún mi, èmi yóò sí fi ìdí ìtẹ́ Rẹ̀ kalẹ̀ títí láé.

13. Èmi yóò jẹ́ bàbá Rẹ̀, Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi. Èmi kì yóò mú ìfẹ́ mi kurò lọ́dọ̀ Rẹ̀ láéláé gẹ́gẹ́ bí mo se mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú Rẹ̀.

14. Èmi yóò gbé e ka orí ilé mi àti ìjọba mi títí láé; ìtẹ́ Rẹ̀ ni a ó fi ìdí Rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.’ ”

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 17