“Nígbà náà, sọ fún ìránṣẹ́ mi Dáfídì pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa alágbára wí: Èmi mú un yín láti pápá oko tútù wá, àní kúrò lẹ́yìn agbo àgùntàn, kí ìwọ lè máa ṣe olórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.