Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 17:2-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nátanì dá Dáfídì lóhùn pé, Ohunkóhun tí o bá ní lọ́kàn, ṣe é nítorí tí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.

3. Ní àsálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Nátanì wá, wí pé:

4. “Lọ sọ fún ìránṣẹ́ mi Dáfídì, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé.

5. Èmi kò tí ì gbé nínú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú Isírẹ́lì jáde wá láti Éjíbítì títí di òní yìí. Èmi ń lọ láti àgọ́ dé àgọ́ àti láti ibùgbé dé ibùgbé.

6. Ni ibi gbogbo tí mo ti bá gbogbo Isírẹ́lì rìn dé, ǹjẹ́ mo wí nǹkankan sí ọ̀kan nínú àwọn adarí Ísírẹ́lì, tí èmí pàṣẹ́ fún láti máa jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn mi, wí pé, “Kí ní ṣe tí ẹ̀yín kò fi kọ́ ilé tí a fi igi kédárì kọ́ fún mi?” ’

7. “Nígbà náà, sọ fún ìránṣẹ́ mi Dáfídì pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa alágbára wí: Èmi mú un yín láti pápá oko tútù wá, àní kúrò lẹ́yìn agbo àgùntàn, kí ìwọ lè máa ṣe olórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.

8. Èmi ti wà pẹ̀lú yín ní, ibi kíbi tí ẹ̀yin ti ń lọ, ẹ̀mi sì ti gé gbogbo àwọn ọ̀ta yín kúrò níwáju yín. Nísinsin yìí Èmi yóò mú kí orúkọ rẹ kí ó dàbí orukọ àwọn ènìyàn ńlá jùlọ̀ tí ó wà ní ayé.

9. Èmi yóò sì pèṣè àyè kan fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, kí wọn kí ó lè ní ilé ti wọn kí a má sì se dàmú wọn mọ́. Àwọn ènìyàn búburú kì yóò ni wọ́n lára mọ́, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti se ní ìbẹ̀rẹ̀.

10. Bí wọ́n sì ti ṣe láti ìgbà tí mo ti yan àwọn aṣájú lórí àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì. Èmi pẹ̀lú yóò sẹ́gun gbogbo àwọn ọ̀ta yín.“ ‘Èmi sọ fún yín pé Olúwa yóò kọ́ ilé kan fún yín:

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 17