Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 11:5-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Wí fún Dáfídì pé, ìwọ kò sì gbọdọ̀ rí nínú ibẹ̀. Bí ó ti lẹ̀jẹ́ wí pé, Dáfídì kọ lu odi alágbára ti Ṣíónì, ìlú ńlá Dáfídì.

6. Dáfídì ti wí pé Ẹnikẹ́ni tí ó bá darí àti kọlu àwọn ará Jébúsì ni yóò di olórí balógun, Jóábù ọmọ Sérúíà lọ sókè lákòókọ́, bẹ́ẹ̀ ni ó sì gba olórí.

7. Dáfídì sì mú lọ sókè ibùgbé nínú odi alágbára, bẹ́ẹ̀ ní a sì ń pè é ni ìlú Dáfídì.

8. Ó sì kọ́ àwọn ìlú náà yíkákiri Rẹ̀, láti ọ̀dọ̀ àwọn alátìlẹ́yìn ibi ìtẹ́jú ilẹ̀ si àyíká ògiri. Nígbà tí Jóábù sì pa ìyókù àwọn ìlú náà run.

9. Nígbà náà Dáfídì sì jẹ́ alágbára kún alágbára nítorí pé Olúwa àwọn ọmọ ogun wà pẹ̀lú Rẹ̀.

10. Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè alágbára ọkùnrin Dáfídì, àwọn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì fún ìjọba Rẹ̀ ní àtìlẹ́yìn tó lágbára láti mú un tàn káàkiri gbogbo ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sèlérí:

11. èyí sì ni iye àwọn alágbára ọkùnrin Dáfídì:Jásóbéámù ọmọ Hákúmónì, òun sì ni olórí nínú àwọn ìjòyè, ó sì gbé ọ̀kọ̀ Rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa ní ogun ẹ̀ẹ̀kan.

12. Lẹ́yìn Rẹ̀ sì ni Élíásárì ọmọ Dódáì àwọn ará Áhóhì, ọ̀kan lára àwọn mẹ́ta ọkùnrin alágbára.

13. Ó sì wà pẹ̀lú Dáfídì ní Pásídámímù nígbà tí àwọn ará Fílístínì kó ara wọn jọ láti jagun, níbi tí ilẹ̀ kan wà tí ó kún fún ọkà báálì. Àwọn ènìyàn sì sálọ kúrò níwájú Fílístínì.

14. Ṣùgbọ́n wọ́n mú ìdúró wọn ní àárin pápá náà. Wọ́n sì gbà a wọ́n sì gún àwọn ará Fílístínì mọ́lẹ̀, Olúwa sì mú ìgbàlà ńlá fún wọn.

15. Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n (30) ìjòyè sọ̀kalẹ̀ tọ́ Dáfídì wá lọ sí orí àpáta nínú ìhò Ádúlámù; Nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ Fílístínì sì dúró ní àfonífojì ní orí òkè Réfáímù.

16. Ní àsìkò náà Dáfídì sì wà nínú ibi gíga àti àwọn ará Fílístínì modi sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

17. Dáfídì sí pòǹgbẹ fún omi ó sì wí pé, Áà, ẹnìkan yóò ha buomi láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu bodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù fún un mu?

Ka pipe ipin 1 Kíróníkà 11