2. Ṣugbọn OLUWA wí fún mi pé, ‘Má bẹ̀rù rẹ̀, nítorí pé mo ti fi òun ati àwọn eniyan rẹ̀ ati ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́, ohun tí o ṣe sí Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ń gbé Heṣiboni ni kí o ṣe sí òun náà.’
3. “OLUWA Ọlọrun wa bá fi Ogu, ọba Baṣani, lé wa lọ́wọ́, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀. A pa wọ́n títí tí kò fi ku ẹnikẹ́ni ninu àwọn eniyan rẹ̀.
4. A gba gbogbo àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ nígbà náà, kò sí ìlú kan tí a kò gbà lọ́wọ́ wọn ninu gbogbo àwọn ìlú wọn. Gbogbo ìlú wọn jẹ́ ọgọta, gbogbo agbègbè Arigobu ati ìjọba Ogu ní Baṣani ni a gbà.
5. Wọ́n mọ odi gíga gíga yípo gbogbo àwọn ìlú ọ̀hún, olukuluku wọ́n sì ní odi tí ó ga ati ẹnubodè pẹlu ọ̀pá ìdábùú, láìka ọpọlọpọ àwọn ìlú kéékèèké tí kò ní odi.
6. A run gbogbo wọn patapata gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe sí Sihoni, ọba Heṣiboni, tí a run gbogbo àwọn ìlú rẹ̀, ati ọkunrin, ati obinrin, ati ọmọde.
7. Ṣugbọn a kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, ati àwọn ohun tí a rí ninu ìlú wọn bí ìkógun.
8. “A gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ àwọn ọba Amori mejeeji tí wọ́n wà ní òkè odò Jọdani nígbà náà. Ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti àfonífojì Anoni títí dé òkè Herimoni.
9. (Herimoni Sirioni ni àwọn ará Sidoni ń pe òkè náà, ṣugbọn àwọn ará Amori ń pè é ní Seniri.)
10. A sì tún gba gbogbo àwọn ìlú wọn tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, gbogbo ilẹ̀ Gileadi ati gbogbo ilẹ̀ Baṣani títí dé Saleka ati Edirei, àwọn ìlú tí ó wà ninu ìjọba Ogu, ọba Baṣani.”
11. (Nítorí pé, Ogu, ọba Baṣani nìkan ni ó kù ninu ìran àwọn Refaimu. Irin ni wọ́n fi ṣe pósí rẹ̀, ó sì wà ní Raba, ní ilẹ̀ àwọn Amoni títí di òní olónìí. Igbọnwọ mẹsan-an ni gígùn pósí náà, ó sì fẹ̀ ní igbọnwọ mẹrin. Igbọnwọ tí ó péye ni wọ́n fi ṣe ìdíwọ̀n pósí náà.)