“Ẹ gbọ́ òwe mìíràn: Baálé ilé kan tí ó gbin àjàrà, ó ṣe ọgbà yìí ká, ó wá ibi ifúntí sínú rẹ̀, ó kọ́ ilé-ìsọ́. Ó sì fi oko náà ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn àgbẹ̀ kan, ó sì lọ sí ìrìnàjò.