27. Kíyèsí i, orúkọ Olúwa ti òkèèrè wápẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti kùrukùruèéfín tí ó nípọn;ètè rẹ̀ kún fún ìbínúahọ́n rẹ̀ sì jẹ́ iná ajónirun.
28. Èémíi rẹ̀ sì dàbí òjò alágbára,tí ó rú sókè dé ọ̀run.Ó jọ àwọn orílẹ̀ èdè nínú asẹ́ ìparun;ó sì fi sí àgbọ̀n àwọn ènìyànkókó kan tí ó ń sì wọ́n lọ́nà.
29. Ẹ̀yin ó sì kọringẹ́gẹ́ bí i ti alẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe àjọyọ̀ àpéjọ mímọ́,ọkàn yín yóò yọ̀gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ènìyàn gòkè lọ pẹ̀lúu fèrèsí orí òkè Olúwa,àní sí àpáta Ísírẹ́lì.
30. Olúwa yóò jẹ́ kí wọn ó gbọ́ ohùn ògo rẹ̀yóò sì jẹ́ kí wọ́n rí apá rẹ̀ tí ó ń bọ̀ wálẹ̀pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti iná ajónirun,pẹ̀lúu mọ̀nàmọ́ná, àrá àti yìnyín.
31. Ohùn Olúwa yóò fọ́ Áṣíríà túútúú,pẹ̀lú ọ̀pá aládé rẹ̀ ni yóò lù wọ́n bolẹ̀.