Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 5:40-48 Yorùbá Bibeli (YCE)

40. Bi ẹnikan ba fẹ sùn ọ ni ile ẹjọ, ti o si gbà ọ li ẹ̀wu lọ, jọwọ agbáda rẹ fun u pẹlu.

41. Ẹnikẹni ti yio ba fi agbara mu ọ lọ si maili kan, bá a de meji.

42. Fifun ẹniti o bère lọwọ rẹ; ati lọdọ ẹniti o nfẹ win lọwọ rẹ, máṣe mu oju kuro.

43. Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wipe, Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ, ki iwọ si korira ọtá rẹ.

44. Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ẹ sure fun awọn ẹniti o nfi nyin ré, ẹ ṣõre fun awọn ti o korira nyin, ki ẹ si gbadura fun awọn ti nfi arankàn ba nyin lò, ti nwọn nṣe inunibini si nyin;

45. Ki ẹnyin ki o le mã jẹ ọmọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun: nitoriti o nmu õrùn rẹ̀ ràn sara enia buburu ati sara enia rere, o si nrọ̀jo fun awọn olõtọ ati fun awọn alaiṣõtọ.

46. Nitori bi ẹnyin ba fẹ awọn ti o fẹ nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? bẹ̃ gẹgẹ ki awọn agbowode nṣe?

47. Bi ẹnyin ba si nkí kìki awọn arakunrin nyin, kili ẹ ṣe jù awọn ẹlomiran lọ? bẹ̃ gẹgẹ ki awọn agbowode nṣe?

48. Nitorina ki ẹnyin ki o pé, bi Baba nyin ti mbẹ li ọrun ti pé.

Ka pipe ipin Mat 5