Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 12:32-44 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Ẹnikẹni ti o ba nsọrọ-odi si Ọmọ-enia, a o dari rẹ̀ jì i; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba nsọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, a ki yio dari rẹ̀ jì i li aiye yi, ati li aiye ti mbọ̀.

33. Sọ igi di rere, eso rẹ̀ a si di rere; tabi sọ igi di buburu, eso rẹ̀ a si di buburu: nitori nipa eso li ã fi mọ igi.

34. Ẹnyin ọmọ paramọlẹ, ẹnyin ti iṣe enia buburu yio ti ṣe le sọ̀rọ rere? nitori ninu ọ̀pọlọpọ ohun inu li ẹnu isọ.

35. Enia rere lati inu iṣura rere ọkàn rẹ̀ ni imu ohun rere jade wá: ati enia buburu lati inu iṣura buburu ni imu ohun buburu jade wá.

36. Ṣugbọn mo wi fun nyin, gbogbo ọ̀rọ wère ti enia nsọ, nwọn o jihìn rẹ̀ li ọjọ idajọ.

37. Nitori nipa ọ̀rọ rẹ li a o fi da ọ lare, nipa ọ̀rọ rẹ li a o si fi da ọ lẹbi.

38. Nigbana li awọn kan ninu awọn akọwe ati Farisi dahùn wipe, Olukọni, awa nwá àmi lọdọ rẹ.

39. Ṣugbọn o dahùn o si wi fun wọn pe, Iran buburu ati iran panṣaga nwá àmi; kò si àmi ti a o fi fun u, bikoṣe àmi Jona wolĩ.

40. Nitori bi Jona ti gbé ọsán mẹta ati oru mẹta ninu ẹja; bẹ̃li Ọmọ-enia yio gbé ọsán mẹta on oru mẹta ni inu ilẹ.

41. Awọn ara Ninefe yio dide pẹlu iran yi li ọjọ idajọ, nwọn, o si da a lẹbi: nitori nwọn ronupiwada nipa iwasu Jona; si wò o, ẹniti o pọ̀ ju Jona lọ mbẹ nihinyi.

42. Ọbabirin gusù yio dide pẹlu iran yi li ọjọ idajọ, yio si da a lẹbi: nitori o ti ikangun aiye wá igbọ́ ọgbọ́n Solomoni; si wò o, ẹniti o pọ̀ ju Solomoni lọ mbẹ nihinyi.

43. Nigbati ẹmi aimọ́ kan ba jade kuro lara enia, a ma rìn kiri ni ibi gbigbẹ, a ma wá ibi isimi, kì si iri.

44. Nigbana ni o wipe, Emi o pada lọ si ile mi, nibiti mo gbé ti jade wá; nigbati o si de, o bá a, o ṣofo, a gbá a mọ́, a si ṣe e li ọṣọ.

Ka pipe ipin Mat 12