Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 6:31-51 Yorùbá Bibeli (YCE)

31. O si wi fun wọn pe, Ẹ wá ẹnyin tikaranyin si ibi ijù li apakan, ki ẹ si simi diẹ: nitori ọ̀pọlọpọ li awọn ti nwá ti nwọn si nlọ, nwọn kò tilẹ ri ãye tobẹ̃ ti nwọn iba fi jẹun.

32. Nwọn si ba ti ọkọ̀ lọ si ibi ijù awọn nikan.

33. Awọn enia si ri wọn nigbati nwọn nlọ, ọ̀pọlọpọ si mọ̀ ọ, nwọn si sare ba ti ẹsẹ lọ sibẹ̀ lati ilu nla gbogbo wá, nwọn si ṣiwaju wọn, nwọn si jùmọ wá sọdọ rẹ̀.

34. Nigbati Jesu jade, o ri ọ̀pọ enia, ãnu wọn ṣe e, nitoriti nwọn dabi awọn agutan ti kò li oluṣọ: o si bẹ̀rẹ si ima kọ́ wọn li ohun pipọ.

35. Nigbati ọjọ si bù lọ tan, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá, wipe, Ibi ijù li eyi, ọjọ si bù lọ tan:

36. Rán wọn lọ, ki nwọn ki o le lọ si àgbegbe ilu, ati si iletò ti o yiká, ki nwọn ki o le rà onjẹ fun ara wọn: nitoriti nwọn kò li ohun ti nwọn o jẹ.

37. Ṣugbọn o dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹ fun wọn li onjẹ. Nwọn si wi fun u pe, Awa o ha lọ irà akara igba owo idẹ ki a si fifun wọn jẹ?

38. O si wi fun wọn pe, Iṣu akara melo li ẹnyin ni? ẹ lọ wò o. Nigbati nwọn si mọ̀, nwọn wipe, Marun, pẹlu ẹja meji.

39. O si wi fun wọn pe, ki nwọn ki o mu gbogbo wọn joko li ẹgbẹgbẹ lori koriko.

40. Nwọn si joko li ẹgbẹgbẹ li ọrọrun ati li aradọta.

41. Nigbati o si mu iṣu akara marun ati ẹja meji na, o gbé oju soke, o si sure, o si bù iṣu akara na, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o gbé e kalẹ niwaju wọn; ati awọn ẹja meji na li o si pín fun gbogbo wọn.

42. Gbogbo wọn si jẹ, nwọn si yó.

43. Nwọn si kó agbọ̀n mejila kún fun ajẹkù, ati ti ẹja pẹlu.

44. Awọn ti o si jẹ ìṣu akara na to iwọn ẹgbẹdọgbọn ọkunrin.

45. Lojukanna li o si rọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati bọ sinu ọkọ̀, ki nwọn ki o si ṣiwaju lọ si apa keji si Betsaida, nigbati on tikararẹ̀ tú awọn enia ká.

46. Nigbati o si rán wọn lọ tan, o gùn ori òke lọ igbadura.

47. Nigbati alẹ si lẹ, ọkọ̀ si wà larin okun, on nikan si wà ni ilẹ.

48. O si ri nwọn nṣiṣẹ ni wiwà ọkọ̀; nitoriti afẹfẹ ṣe ọwọ òdi si wọn: nigbati o si di ìwọn iṣọ kẹrin oru, o tọ̀ wọn wá, o nrìn lori okun, on si nfẹ ré wọn kọja.

49. Ṣugbọn nigbati nwọn ri ti o nrìn loju omi, nwọn ṣebi iwin ni, nwọn si kigbe soke:

50. Nitori gbogbo wọn li o ri i, ti ẹ̀ru si ba wọn. Ṣugbọn lojukanna o si ba wọn sọ̀rọ, o si wi fun wọn pe, Ẹ tújuka: Emi ni; ẹ má bẹ̀ru.

51. O si wọ̀ inu ọkọ̀ tọ̀ wọn lọ; afẹfẹ si da: ẹ̀ru si ba wọn rekọja gidigidi ninu ara wọn, ẹnu si yà wọn.

Ka pipe ipin Mak 6