Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 6:20-37 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Nitori Herodu bẹ̀ru Johanu, o si mọ̀ ọ li olõtọ enia ati ẹni mimọ́, o si ntọju rẹ̀; nigbati o gbọrọ rẹ̀, o ṣe ohun pipọ, o si fi ayọ̀ gbọrọ rẹ̀.

21. Nigbati ọjọ ti o wọ̀ si de, ti Herodu sàse ọjọ ibí rẹ̀ fun awọn ijoye rẹ̀, awọn balogun, ati awọn olori ni Galili;

22. Nigbati ọmọbinrin Herodia si wọle, ti o si njó, o mu inu Herodu dùn ati awọn ti o ba a joko, ọba si wi fun ọmọbinrin na pe, Bère ohunkohun ti iwọ fẹ lọwọ mi, emi o si fifun ọ.

23. O si bura fun u, wipe, Ohunkohun ti iwọ ba bere lọwọ mi, emi o si fifun ọ, titi fi de idameji ijọba mi.

24. O si jade lọ, o wi fun iya rẹ̀ pe, Kini ki emi ki o bère? On si wipe, Ori Johanu Baptisti.

25. Lojukanna, o si wọle tọ̀ ọba wá kánkan, o bère, wipe, emi nfẹ ki iwọ ki o fi ori Johanu Baptisti fun mi ninu awopọkọ nisisiyi.

26. Inu ọba si bajẹ gidigidi; ṣugbọn nitori ibura rẹ̀, ati nitori awọn ti o bá a joko pọ̀, kò si fẹ ikọ̀ fun u.

27. Lọgan ọba si rán ẹṣọ́ kan, o fi aṣẹ fun u pe, ki o gbé ori rẹ̀ wá: o si lọ, o bẹ́ Johanu lori ninu tubu.

28. O si gbé ori rẹ̀ wá ninu awopọkọ, o si fi fun ọmọbinrin na: ọmọbinrin na si fi fun iya rẹ̀.

29. Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbọ́, nwọn wá, nwọn gbé okú rẹ̀, nwọn si lọ tẹ́ ẹ sinu ibojì.

30. Awọn aposteli si kó ara wọn jọ sọdọ Jesu, nwọn si ròhin ohungbogbo ti nwọn ti ṣe fun u, ati ohungbogbo ti nwọn ti kọni.

31. O si wi fun wọn pe, Ẹ wá ẹnyin tikaranyin si ibi ijù li apakan, ki ẹ si simi diẹ: nitori ọ̀pọlọpọ li awọn ti nwá ti nwọn si nlọ, nwọn kò tilẹ ri ãye tobẹ̃ ti nwọn iba fi jẹun.

32. Nwọn si ba ti ọkọ̀ lọ si ibi ijù awọn nikan.

33. Awọn enia si ri wọn nigbati nwọn nlọ, ọ̀pọlọpọ si mọ̀ ọ, nwọn si sare ba ti ẹsẹ lọ sibẹ̀ lati ilu nla gbogbo wá, nwọn si ṣiwaju wọn, nwọn si jùmọ wá sọdọ rẹ̀.

34. Nigbati Jesu jade, o ri ọ̀pọ enia, ãnu wọn ṣe e, nitoriti nwọn dabi awọn agutan ti kò li oluṣọ: o si bẹ̀rẹ si ima kọ́ wọn li ohun pipọ.

35. Nigbati ọjọ si bù lọ tan, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá, wipe, Ibi ijù li eyi, ọjọ si bù lọ tan:

36. Rán wọn lọ, ki nwọn ki o le lọ si àgbegbe ilu, ati si iletò ti o yiká, ki nwọn ki o le rà onjẹ fun ara wọn: nitoriti nwọn kò li ohun ti nwọn o jẹ.

37. Ṣugbọn o dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹ fun wọn li onjẹ. Nwọn si wi fun u pe, Awa o ha lọ irà akara igba owo idẹ ki a si fifun wọn jẹ?

Ka pipe ipin Mak 6