Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kol 1:15-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ẹniti iṣe aworan Ọlọrun ti a kò ri, akọbi gbogbo ẹda:

16. Nitori ninu rẹ̀ li a ti dá ohun gbogbo, ohun ti mbẹ li ọrun, ati ohun ti mbẹ li aiye, eyiti a ri, ati eyiti a kò ri, nwọn iba ṣe itẹ́, tabi oye, tabi ijọba, tabi ọla: nipasẹ rẹ̀ li a ti dá ohun gbogbo, ati fun u:

17. On si wà ṣaju ohun gbogbo, ati ninu rẹ̀ li ohun gbogbo duro ṣọkan.

18. On si jẹ ori fun ara, eyini ni ìjọ: ẹniti iṣe ipilẹṣẹ, akọbi lati inu okú wá; pe, ninu ohun gbogbo ki on ki o le ni ipò ti o ga julọ.

19. Nitori didun inu Baba ni pe ki ẹkún gbogbo le mã gbé inu rẹ̀;

20. Ati nipasẹ rẹ̀ lati bá ohun gbogbo lajà, lẹhin ti o ti fi ẹjẹ agbelebu rẹ̀ pari ija; mo ni, nipasẹ rẹ̀, nwọn iba ṣe ohun ti mbẹ li aiye, tabi ohun ti mbẹ li ọrun.

21. Ati ẹnyin ti o ti jẹ alejò ati ọtá rí li ọkàn nyin ni iṣẹ buburu nyin, ẹnyin li o si ti bá laja nisisiyi,

22. Ninu ara rẹ̀ nipa ikú, lati mu nyin wá iwaju rẹ̀ ni mimọ́ ati ailabawọn ati ainibawi;

23. Bi ẹnyin ba duro ninu igbagbọ́, ti ẹ fẹsẹmulẹ ti ẹ si duro ṣinṣin, ti ẹ kò si yẹsẹ kuro ninu ireti ihinrere ti ẹnyin ti gbọ́, eyiti a si ti wasu rẹ̀ ninu gbogbo ẹda ti mbẹ labẹ ọrun, eyiti a fi emi Paulu ṣe iranṣẹ fun.

24. Nisisiyi emi nyọ̀ ninu ìya mi nitori nyin, emi si nmu ipọnju Kristi ti o kù lẹhin kún li ara mi, nitori ara rẹ̀, ti iṣe ìjọ:

Ka pipe ipin Kol 1