Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joh 10:19-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Nitorina iyapa tun wà larin awọn Ju nitori ọ̀rọ wọnyi.

20. Ọpọ ninu wọn si wipe, O li ẹmi èṣu, ori rẹ̀ si bajẹ; ẽṣe ti ẹnyin ngbọ̀rọ rẹ̀?

21. Awọn miran wipe, Wọnyi kì iṣe ọ̀rọ ẹniti o li ẹmi èsu. Ẹmi èsu le là oju awọn afọju bi?

22. O si jẹ ajọ ọdun iyasimimọ́ ni Jerusalemu, igba otutù ni.

23. Jesu si nrìn ni tẹmpili, nì ìloro Solomoni.

24. Nitorina awọn Ju wá duro yi i ká, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ó ti mu wa ṣe iyemeji pẹ to? Bi iwọ ni iṣe Kristi na, wi fun wa gbangba.

25. Jesu da wọn lohùn wipe, Emi ti wi fun nyin, ẹnyin kò si gbagbọ́; iṣẹ ti emi nṣe li orukọ Baba mi, awọn ni njẹri mi.

26. Ṣugbọn ẹnyin kò gbagbọ́, nitori ẹnyin kò si ninu awọn agutan mi, gẹgẹ bi mo ti wi fun nyin.

27. Awọn agutan mi ngbọ ohùn mi, emi si mọ̀ wọn, nwọn a si ma tọ̀ mi lẹhin:

28. Emi si fun wọn ni ìye ainipẹkun; nwọn kì o si ṣegbé lailai, kò si si ẹniti o le já wọn kuro li ọwọ́ mi.

29. Baba mi, ẹniti o fi wọn fun mi, pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò si si ẹniti o le já wọn kuro li ọwọ́ Baba mi.

30. Ọ̀kan li emi ati Baba mi jasi.

31. Awọn Ju si tún he okuta, lati sọ lù u.

Ka pipe ipin Joh 10