orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Tes 3 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ẹ Gbadura Fún Wa

1. LAKOTAN, ará, ẹ mã gbadura fun wa, ki ọ̀rọ Oluwa le mã sáre, ki o si jẹ ãyìn logo, ani gẹgẹ bi o ti ri lọdọ nyin:

2. Ati ki a le gbà wa lọwọ awọn aṣodi ati awọn enia buburu: nitoripe ki iṣe gbogbo enia li o gbagbọ́.

3. Ṣugbọn olododo li Oluwa, ẹniti yio fi ẹsẹ nyin mulẹ, ti yio si pa nyin mọ́ kuro ninu ibi.

4. Awa si ni igbẹkẹle ninu Oluwa niti nyin, pe nkan wọnni ti a palaṣẹ fun nyin li ẹnyin nṣe ti ẹ o si mã ṣe.

5. Ki Oluwa ki o si mã tọ́ ọkan nyin sinu ifẹ Ọlọrun, ati sinu sũru Kristi.

Ìkìlọ̀ Nípa Àwọn Onímẹ̀ẹ́lẹ́

6. Awa si paṣẹ fun nyin, ará, li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa, ki ẹnyin ki o yẹra kuro lọdọ olukuluku arakunrin, ti nrin ségesège, ti kì iṣe gẹgẹ bi ìlana ti nwọn ti gbà lọwọ wa.

7. Nitori ẹnyin tikaranyin mọ̀ bi o ti yẹ ki ẹnyin na farawe wa: nitori awa kò rin ségesège larin nyin;

8. Bẹ̃li awa kò si jẹ onjẹ ẹnikẹni lọfẹ; ṣugbọn ninu ãpọn ati lãlã li a nṣiṣẹ́ lọsan ati loru, ki awa ki o ma bã dẹruba ẹnikẹni ninu nyìn:

9. Kì iṣe pe awa kò li agbara, ṣugbọn awa nfi ara wa ṣe apẹrẹ fun nyin ki ẹnyin kì o le mã farawe wa.

10. Nitori nigbati awa tilẹ wà pẹlu nyin, eyi li awa palaṣẹ fun nyin, pe bi ẹnikẹni kò bá fẹ ṣiṣẹ, ki o maṣe jẹun.

11. Nitori awa gburo awọn kan ti nrin ségesège larin nyìn ti nwọn kò nṣiṣẹ rara, ṣugbọn nwọn jẹ àtọjú-ile-kiri.

12. Njẹ irú awọn ẹni bẹ̃ li awa npaṣẹ fun, ti a si nrọ̀ ninu Oluwa Jesu Kristi, pe ki nwọn ki o mã fi ìwa pẹlẹ ṣiṣẹ, ki nwọn ki o si mã jẹ onjẹ awọn tikarawọn.

13. Ṣugbọn ẹnyin, ará, ẹ máṣe ṣãrẹ̀ ni rere iṣe.

14. Bi ẹnikẹni kò ba si gbà ọ̀rọ wa gbọ́ nipa iwe yi, ẹ sami si oluwarẹ, ki ẹ má si ṣe ba a kẹgbẹ, ki oju ki o le tì i.

15. Sibẹ ẹ máṣe kà a si ọtá, ṣugbọn ẹ mã gbà a niyanju bi arakunrin.

Gbolohun Ìparí

16. Njẹ ki Oluwa alafia tikararẹ̀ mã fun nyin ni alafia nigbagbogbo lọna gbogbo. Ki Oluwa ki o pẹlu gbogbo nyin.

17. Ikíni emi Paulu lati ọwọ́ ara mi, eyiti iṣe àmi ninu gbogbo iwe; bẹ̃ni mo nkọwe.

18. Ore-ọfẹ Oluwa wa Jesu Kristi ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.