orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Tes 1 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ìkíni

1. PAULU, ati Silfanu, ati Timotiu, si ijọ Tessalonika, ninu Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kristi Oluwa:

2. Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba, ati Jesu Kristi Oluwa.

Ìdájọ́ Nígbà Tí Jesu Bá Dé

3. Iṣẹ wa ni lati mã dupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo nitori nyin, ará, ani gẹgẹ bi o ti yẹ, nitoripe igbagbọ́ nyin ndàgba gidigidi, ati ifẹ olukuluku nyin gbogbo si ara nyin ndi pupọ;

4. Tobẹ̃ ti awa tikarawa nfi nyin ṣogo ninu ijọ Ọlọrun, nitori sũru ati igbagbọ́ nyin ninu gbogbo inunibini ati wahalà nyin ti ẹnyin nfarada,

5. Eyiti iṣe àmi idajọ ododo Ọlọrun ti o daju, ki a le kà nyin yẹ fun ijọba Ọlọrun, nitori eyiti ẹnyin pẹlu ṣe njìya:

6. Bi o ti jẹ pe ohun ododo ni fun Ọlọrun lati fi ipọnju gbẹsan lara awọn ti npọ́n nyin loju,

7. Ati fun ẹnyin, ti a npọ́n loju, isimi pẹlu wa, nigba ifarahàn Jesu Oluwa lati ọrun wá ninu ọwọ́ ina pẹlu awọn angẹli alagbara rẹ̀,

8. Ẹniti yio san ẹsan fun awọn ti kò mọ Ọlọrun, ti nwọn kò si gbà ihinrere Jesu Oluwa wa gbọ́:

9. Awọn ẹniti yio jiya iparun ainipẹkun lati iwaju Oluwa wá, ati lati inu ogo agbara rẹ̀,

10. Nigbati o ba de lati jẹ ẹni ãyìn logo ninu awọn enia mimọ́ rẹ̀, ati ẹni iyanu ninu gbogbo awọn ti o gbagbọ́ (nitori a ti gbà ẹrí ti a jẹ fun nyin gbọ) li ọjọ na.

11. Nitori eyiti awa pẹlu ngbadura fun nyin nigbagbogbo, pe ki Ọlọrun wa ki o le kà nyin yẹ fun ìpe nyin, ki o le mu gbogbo ifẹ ohun rere ati iṣẹ igbagbọ́ ṣẹ ni agbara:

12. Ki a le yìn orukọ Jesu Oluwa wa logo ninu nyin, ati ẹnyin ninu rẹ̀, gẹgẹ bi ore-ọfẹ Ọlọrun wa ati ti Jesu Kristi Oluwa.