Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 7:29-40 Yorùbá Bibeli (YCE)

29. Mose si sá nitori ọ̀rọ yi, o si wa ṣe atipo ni ilẹ Midiani, nibiti o gbé bí ọmọ meji.

30. Nigbati ogoji ọdún si pé, angẹli Oluwa farahàn a ni ijù, li òke Sinai, ninu ọwọ́ iná ni igbẹ́.

31. Nigbati Mose si ri i, ẹnu yà a si iran na: nigbati o si sunmọ ọ lati wò o fín, ohùn Oluwa kọ si i,

32. Wipe, Emi li Ọlọrun awọn baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu. Mose si warìri, kò si daṣa lati wò o mọ́.

33. Oluwa si wi fun u pe, Tú bata rẹ kuro li ẹsẹ rẹ: nitori ibi ti iwọ gbé duro nì ilẹ mimọ́ ni.

34. Ni riri mo ti ri ipọnju awọn enia mi ti mbẹ ni Egipti, mo si ti gbọ́ gbigbin wọn, mo si sọkalẹ wá lati gbà wọn. Wá nisisiyi, emi o si rán ọ lọ si Egipti.

35. Mose na yi ti nwọn kọ̀, wipe, Tali o fi ọ jẹ olori ati onidajọ? on na li Ọlọrun rán lọ lati ọwọ́ angẹli, ti o farahàn a ni igbẹ́, lati ṣe olori ati oludande.

36. On li o mu wọn jade, lẹhin igbati o ṣe iṣẹ iyanu ati iṣẹ àmi ni ilẹ Egipti, ati li Okun pupa, ati li aginjù li ogoji ọdún.

37. Eyi ni Mose na ti o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Woli kan li Oluwa Ọlọrun nyin yio gbé dide fun nyin ninu awọn arakunrin nyin, bi emi; on ni ki ẹ gbọ́ tirẹ.

38. Eyi na li ẹniti o wà ninu ijọ ni ijù pẹlu angẹli na ti o ba a sọ̀rọ li òke Sinai, ati pẹlu awọn baba wa: ẹniti o gbà ọ̀rọ ìye lati fifun wa:

39. Ẹniti awọn baba wa kò fẹ gbọ́ tirẹ, ṣugbọn nwọn tì i kuro lọdọ wọn, nwọn si yipada li ọkàn wọn si Egipti;

40. Nwọn wi fun Aaroni pe, Dà oriṣa fun wa ti yio ma tọ̀na ṣaju wa: nitori bi o ṣe ti Mose yi ti o mu wa ti ilẹ Egipti jade wá, a kò mọ̀ ohun ti o ṣe e.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 7