Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 26:1-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AGRIPPA si wi fun Paulu pe, A fun ọ làye lati sọ ti ẹnu rẹ. Nigbana ni Paulu nawọ́, o si sọ ti ẹnu rẹ̀ pe:

2. Agrippa ọba, inu emi tikarami dùn nitoriti emi o wi ti ẹnu mi loni niwaju rẹ, niti gbogbo nkan ti awọn Ju nfi mi sùn si.

3. Pãpã bi iwọ ti mọ̀ gbogbo iṣe ati ọ̀ran ti mbẹ lãrin awọn Ju dajudaju, nitorina emi bẹ̀ ọ ki iwọ ki o fi sũru gbọ temi.

4. Iwà aiye mi lati igba ewe mi, bi o ti ri lati ibẹrẹ, lãrin orilẹ-ede mi ati ni Jerusalemu, ni gbogbo awọn Ju mọ̀.

5. Nitori nwọn mọ̀ mi lati ipilẹṣẹ, bi nwọn ba fẹ́ jẹri pe, gẹgẹ bi ẹya ìsin wa ti o le julọ, Farisi li emi.

6. Ati nisisiyi nitori ireti ileri ti Ọlọrun ti ṣe fun awọn baba wa ni mo ṣe duro nihin fun idajọ.

7. Ileri eyiti awọn ẹ̀ya wa mejejila ti nfi itara sin Ọlọrun lọsan ati loru ti nwọn nreti ati ri gba. Nitori ireti yi li awọn Ju ṣe nfi mi sùn, Agrippa Ọba.

8. Ẽṣe ti ẹnyin fi rò o si ohun ti a kò le gbagbọ́ bi Ọlọrun ba jí okú dide?

9. Emi tilẹ rò ninu ara mi nitõtọ pe, o yẹ ki emi ki o ṣe ọpọlọpọ ohun òdi si orukọ Jesu ti Nasareti.

10. Eyi ni mo si ṣe ni Jerusalemu: awọn pipọ ninu awọn enia mimọ́ ni mo há mọ́ inu tubu, nigbati mo ti gbà aṣẹ lọdọ awọn olori alufa; nigbati nwọn si npa wọn, mo li ohùn si i.

11. Nigbapipọ ni mo ṣẹ́ wọn niṣẹ ninu gbogbo sinagogu, mo ndù u lati mu wọn sọ ọrọ-odi; nigbati mo ṣoro si wọn gidigidi, mo ṣe inunibini si wọn de àjeji ilu.

12. Ninu rẹ̀ na bi mo ti nlọ si Damasku ti emi ti ọlá ati aṣẹ ikọ̀ lati ọdọ awọn olori alufa lọ,

13. Li ọsangangan, Ọba, mo ri imọlẹ kan lati ọrun wá, o jù riràn õrùn lọ, o mọlẹ yi mi ká, ati awọn ti o mba mi rè ajo.

14. Nigbati gbogbo wa si ṣubu lulẹ, mo gbọ́ ohùn ti nfọ̀ si mi ni ède Heberu pe, Saulu, Saulu, ẽṣe ti iwọ fi nṣe inunibini si mi? Ohun irora ni fun ọ lati tapá si ẹgún.

15. Emi si wipe, Iwọ tani, Oluwa? Oluwa si wipe, Emi ni Jesu ti iwọ nṣe inunibini si.

16. Ṣugbọn dide, ki o si fi ẹsẹ rẹ tẹlẹ: nitori eyi ni mo ṣe farahàn ọ lati yàn ọ ni iranṣẹ ati ẹlẹri, fun ohun wọnni ti iwọ ti ri, ati ohun wọnni ti emi ó fi ara hàn fun ọ;

17. Emi o ma gbà ọ lọwọ awọn enia, ati lọwọ awọn Keferi, ti emi rán ọ si nisisiyi,

18. Lati là wọn li oju, ki nwọn ki o le yipada kuro ninu òkunkun si imọlẹ, ati kuro lọwọ agbara Satani si Ọlọrun, ki nwọn ki o le gbà idariji ẹ̀ṣẹ, ati ogún pẹlu awọn ti a sọ di mimọ́ nipa igbagbọ ninu mi.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 26