Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 2:28-45 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Iwọ mu mi mọ̀ ọ̀na iye; iwọ ó mu mi kún fun ayọ̀ ni iwaju rẹ.

29. Ará, ẹ jẹ ki emi ki o sọ fun nyin gbangba niti Dafidi baba nla pe, o kú, a si sin i, ibojì rẹ̀ si mbẹ lọdọ wa titi o fi di oni yi.

30. Nitoriti iṣe woli, ati bi o ti mọ̀ pe, Ọlọrun ti fi ibura ṣe ileri fun u pe, Ninu irú-ọmọ inu rẹ̀, on ó mu ọ̀kan ijoko lori itẹ́ rẹ̀;

31. O ri eyi tẹlẹ̀, o sọ ti ajinde Kristi pe, a kò fi ọkàn rẹ̀ silẹ ni ipò-okù, bẹ̃li ara rẹ̀ kò ri idibajẹ.

32. Jesu na yi li Ọlọrun ti ji dide, ẹlẹri eyiti gbogbo wa iṣe.

33. Nitorina bi a ti fi ọwọ́ ọtún Ọlọrun gbe e ga, ti o si ti gbà ileri Ẹmí Mimọ́ lati ọdọ Baba, o tú eyi silẹ, ti ẹnyin ri, ti ẹ si gbọ́.

34. Dafidi kò sá gòke lọ si ọrun: ṣugbọn on tikararẹ̀ wipe, OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Joko li ọwọ́ ọtún mi,

35. Titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apotì itisẹ rẹ.

36. Njẹ ki gbogbo ile Israeli ki o mọ̀ dajudaju pe, Ọlọrun ti fi Jesu na, ti ẹnyin kàn mọ agbelebu, jẹ Oluwa ati Kristi.

37. Nigbati nwọn si gbọ́, ọkàn wọn gbọgbẹ, nwọn si sọ fun Peteru ati awọn aposteli iyokù pe, Ará, kini ki awa ki o ṣe?

38. Peteru si wi fun wọn pe, Ẹ ronupiwada, ki a si baptisi olukuluku nyin li orukọ Jesu Kristi fun idariji ẹ̀ṣẹ nyin, ẹnyin o si gbà ẹbun Ẹmi Mimọ́.

39. Nitori fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jìna rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pè.

40. Ati ọ̀rọ pupọ miran li o fi njẹri ti o si nfi ngbà wọn niyanju wipe, Ẹ gbà ara nyin là lọwọ iran arekereke yi.

41. Nitorina awọn ti o si fi ayọ̀ gbà ọ̀rọ rẹ̀ a baptisi wọn: li ọjọ na a si kà ìwọn ẹgbẹdogun ọkàn kún wọn.

42. Nwọn si duro ṣinṣin ninu ẹkọ́ awọn aposteli, ati ni idapọ, ni bibu akara ati ninu adura.

43. Ẹ̀rù si ba gbogbo ọkàn: iṣẹ iyanu ati iṣẹ àmi pipọ li a ti ọwọ́ awọn aposteli ṣe.

44. Gbogbo awọn ti o si gbagbọ́ wà ni ibikan, nwọn ni ohun gbogbo ṣọkan;

45. Nwọn si ntà ohun ini ati ẹrù wọn, nwọn si npín wọn fun olukuluku, gẹgẹ bi ẹnikẹni ti ṣe alaini.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 2