Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 18:13-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Nwọn wipe, ọkunrin yi nyi awọn enia li ọkàn pada, lati mã sin Ọlọrun lodi si ofin.

14. Nigbati Paulu nfẹ ati dahùn, Gallioni wi fun awọn Ju pe, Ibaṣepe ọ̀ran buburu tabi ti jagidijagan kan ni, bi ọ̀rọ ti ri, ẹnyin Ju, emi iba gbè nyin:

15. Ṣugbọn bi o ba ṣe ọ̀ran nipa ọ̀rọ ati orukọ, ati ti ofin nyin ni, ki ẹnyin ki o bojuto o fun ara nyin, nitoriti emi kò fẹ ṣe onidajọ nkan bawọnni.

16. O si lé wọn kuro ni ibi itẹ idajọ.

17. Gbogbo awọn Hellene si mu Sostene, olori sinagogu, nwọn si lù u niwaju itẹ idajọ. Gallioni kò si ṣú si nkan wọnyi.

18. Paulu si duro si i nibẹ̀ li ọjọ pipọ, nigbati o si dágbere fun awọn arakunrin, o ba ti ọkọ̀ lọ si Siria, ati Priskilla ati Akuila pẹlu rẹ̀; o ti fá ori rẹ̀ ni Kenkrea: nitoriti o ti jẹjẹ.

19. O si sọkalẹ wá si Efesu, o si fi wọn silẹ nibẹ̀: ṣugbọn on tikararẹ̀ wọ̀ inu sinagogu lọ, o si ba awọn Ju fi ọrọ we ọrọ.

20. Nigbati nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o ba awọn joko diẹ si i, o kọ̀;

21. Ṣugbọn o dágbere fun wọn, o si wipe, Emi kò gbọdọ ṣaima ṣe ajọ ọdún ti mbọ̀ yi ni Jerusalemu bi o ti wù ki o ri: ṣugbọn emi ó tún pada tọ̀ nyin wá, bi Ọlọrun ba fẹ. O si ṣikọ̀ ni Efesu.

22. Nigbati o si ti gúnlẹ ni Kesarea, ti o goke, ti o si ki ijọ, o sọkalẹ lọ si Antioku.

23. Nigbati o si gbé ọjọ diẹ nibẹ̀, o lọ, o si kọja ni ilẹ Galatia on Frigia lẹsẹsẹ, o nmu gbogbo awọn ọmọ-ẹhin li ọkàn le.

24. Ju kan si wà ti a npè ni Apollo, ti a bí ni Aleksandria, ọkunrin ọlọrọ li ẹnu, ti o pọ̀ ni iwe-mimọ́, o wá si Efesu.

25. Ọkunrin yi li a ti kọ́ ni ọ̀na ti Oluwa; o si ṣe ẹniti o gboná li ọkàn, o nfi ãyan nsọ̀rọ, o si nkọ́ni ni nkan ti Oluwa; kìki baptismu ti Johanu li o mọ̀.

26. O si bẹ̀rẹ si fi igboiya sọrọ ni sinagogu: nigbati Akuila on Priskilla ti gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, nwọn mu u si ọdọ nwọn si tubọ sọ idi ọ̀na Ọlọrun fun u dajudaju.

27. Nigbati o si nfẹ kọja lọ si Akaia, awọn arakunrin gba a ni iyanju, nwọn si kọwe si awọn ọmọ-ẹhin ki nwọn ki o gba a: nigbati o si de, o ràn awọn ti o gbagbọ́ nipa ore-ọfẹ lọwọ pupọ.

28. Nitoriti o sọ asọye fun awọn Ju ni gbangba, o nfi i hàn ninu iwe-mimọ́ pe, Jesu ni Kristi.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 18