Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 17:23-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Nitori bi mo ti nkọja lọ, ti mo wò ohun wọnni ti ẹnyin nsìn, mo si ri pẹpẹ kan ti a kọ akọle yi si, FUN ỌLỌRUN AIMỌ̀. Njẹ ẹniti ẹnyin nsìn li aimọ̀ on na li emi nsọ fun nyin.

24. Ọlọrun na ti o da aiye ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, on na ti iṣe Oluwa ọrun on aiye, kì igbé ile ti a fi ọwọ́ kọ́;

25. Bẹ̃ni a kì ifi ọwọ́ enia sìn i, bi ẹnipe o nfẹ nkan, on li o fi ìye ati ẽmi ati ohun gbogbo fun gbogbo enia,

26. O si ti fi ẹ̀jẹ kanna da gbogbo orilẹ-ede lati tẹ̀do si oju agbaiye, o si ti pinnu akokò ti a yàn tẹlẹ, ati àla ibugbe wọn;

27. Ki nwọn ki o le mã wá Oluwa, boya bi ọkàn wọn ba le fà si i, ti wọn si ri i, bi o tilẹ ṣe pe kò jina si olukuluku wa:

28. Nitori ninu rẹ̀ li awa gbé wà li ãye, ti awa nrìn kiri, ti a si li ẹmí wa; bi awọn kan ninu awọn olorin, ẹnyin tikaranyin ti wipe, Awa pẹlu si jẹ ọmọ rẹ̀.

29. Njẹ bi awa ba ṣe ọmọ Ọlọrun, kò yẹ fun wa ki a rò pe, Iwa-Ọlọrun dabi wura, tabi fadaka, tabi okuta, ti a fi ọgbọ́n ati ihumọ enia ṣe li ọnà.

30. Pẹlupẹlu igba aimọ̀ yi li Ọlọrun ti foju fò da; ṣugbọn nisisiyi o paṣẹ fun gbogbo enia nibi gbogbo lati ronupiwada:

31. Niwọnbi o ti da ọjọ kan, ninu eyi ti yio ṣe idajọ aiye li ododo, nipasẹ ọkunrin na ti o ti yàn, nigbati o ti fi ohun idaniloju fun gbogbo enia, niti o jí i dide kuro ninu okú.

32. Nigbati nwọn ti gbọ́ ti ajinde okú, awọn miran nṣẹ̀fẹ: ṣugbọn awọn miran wipe, Awa o tún nkan yi gbọ́ li ẹnu rẹ.

33. Bẹ̃ni Paulu si jade kuro larin wọn.

34. Ṣugbọn awọn ọkunrin kan fi ara mọ́ ọ, nwọn si gbagbọ́: ninu awọn ẹniti Dionisiu ara Areopagu wà, ati obinrin kan ti a npè ni Damari, ati awọn miran pẹlu wọn.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 17