Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 17:17-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Nitorina o mba awọn Ju fi ọ̀rọ̀ we ọ̀rọ̀ ninu sinagogu, ati awọn olufọkansin, ati awọn ti o mba pade lọja lojojumọ.

18. Ninu awọn Epikurei pẹlu, ati awọn ọjọgbọ́n Stoiki kótì i. Awọn kan si nwipe, Kili alahesọ yi yio ri wi? awọn miran si wipe, O dabi oniwasu ajeji oriṣa: nitoriti o nwasu Jesu, on ajinde fun wọn.

19. Nwọn si mu u, nwọn si fà a lọ si Areopagu, nwọn wipe, A ha le mọ̀ kili ẹkọ́ titun ti iwọ nsọrọ rẹ̀ yi jẹ́.

20. Nitoriti iwọ mu ohun ajeji wá si etí wa: awa si nfẹ mọ̀ kini itumọ nkan wọnyi.

21. Nitori gbogbo awọn ará Ateni, ati awọn alejò ti nṣe atipo nibẹ kì iṣe ohun miran jù, ki a mã sọ tabi ki a ma gbọ́ ohun titun lọ.

22. Paulu si dide duro larin Areopagu, o ni, Ẹnyin ará Ateni, mo woye pe li ohun gbogbo ẹ kun fun oniruru isin ju.

23. Nitori bi mo ti nkọja lọ, ti mo wò ohun wọnni ti ẹnyin nsìn, mo si ri pẹpẹ kan ti a kọ akọle yi si, FUN ỌLỌRUN AIMỌ̀. Njẹ ẹniti ẹnyin nsìn li aimọ̀ on na li emi nsọ fun nyin.

24. Ọlọrun na ti o da aiye ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, on na ti iṣe Oluwa ọrun on aiye, kì igbé ile ti a fi ọwọ́ kọ́;

25. Bẹ̃ni a kì ifi ọwọ́ enia sìn i, bi ẹnipe o nfẹ nkan, on li o fi ìye ati ẽmi ati ohun gbogbo fun gbogbo enia,

26. O si ti fi ẹ̀jẹ kanna da gbogbo orilẹ-ede lati tẹ̀do si oju agbaiye, o si ti pinnu akokò ti a yàn tẹlẹ, ati àla ibugbe wọn;

27. Ki nwọn ki o le mã wá Oluwa, boya bi ọkàn wọn ba le fà si i, ti wọn si ri i, bi o tilẹ ṣe pe kò jina si olukuluku wa:

28. Nitori ninu rẹ̀ li awa gbé wà li ãye, ti awa nrìn kiri, ti a si li ẹmí wa; bi awọn kan ninu awọn olorin, ẹnyin tikaranyin ti wipe, Awa pẹlu si jẹ ọmọ rẹ̀.

29. Njẹ bi awa ba ṣe ọmọ Ọlọrun, kò yẹ fun wa ki a rò pe, Iwa-Ọlọrun dabi wura, tabi fadaka, tabi okuta, ti a fi ọgbọ́n ati ihumọ enia ṣe li ọnà.

30. Pẹlupẹlu igba aimọ̀ yi li Ọlọrun ti foju fò da; ṣugbọn nisisiyi o paṣẹ fun gbogbo enia nibi gbogbo lati ronupiwada:

31. Niwọnbi o ti da ọjọ kan, ninu eyi ti yio ṣe idajọ aiye li ododo, nipasẹ ọkunrin na ti o ti yàn, nigbati o ti fi ohun idaniloju fun gbogbo enia, niti o jí i dide kuro ninu okú.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 17