Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 10:23-41 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Nigbana li o pè wọn wọle, o si fi wọn wọ̀. Nijọ keji o si dide, o ba wọn lọ, ninu awọn arakunrin ni Joppa si ba a lọ.

24. Nijọ keji nwọn si wọ̀ Kesarea. Korneliu si ti nreti wọn, o si ti pè awọn ibatan ati awọn ọrẹ́ rẹ̀ timọtimọ jọ.

25. O si ṣe bi Peteru ti nwọle, Korneliu pade rẹ̀, o wolẹ li ẹsẹ rẹ̀, o si foribalẹ fun u.

26. Ṣugbọn Peteru gbé e dide, o ni, Dide; enia li emi tikarami pẹlu.

27. Bi o si ti mba a sọ̀rọ, o wọle, o si bá awọn enia pipọ ti nwọn pejọ.

28. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ bi o ti jẹ ẽwọ̀ fun ẹniti iṣe Ju, lati ba ẹniti iṣe ara ilẹ miran kẹgbẹ, tabi lati tọ̀ ọ wá; ṣugbọn Ọlọrun ti fihàn mi pe, ki emi ki o máṣe pè ẹnikẹni li ẽwọ̀ tabi alaimọ́.

29. Nitorina ni mo si ṣe wá li aijiyàn, bi a ti ranṣẹ pè mi: njẹ mo bère, nitori kili ẹnyin ṣe ranṣẹ pè mi?

30. Korneliu si dahùn pe, Ni ijẹrin, mo nṣe adura wakati kẹsan ọjọ ni ile mi titi di akoko yi, si wo o, ọkunrin kan alaṣọ àla duro niwaju mi.

31. O si wipe, Korneliu, a gbọ́ adura rẹ, ọrẹ-ãnu rẹ si wà ni iranti niwaju Ọlọrun.

32. Njẹ ranṣẹ lọ si Joppa, ki o si pè Simoni wá, ẹniti apele rẹ̀ jẹ Peteru; o wọ̀ ni ile Simoni alawọ leti okun: nigbati o ba de, yio sọ̀rọ fun ọ.

33. Nitorina ni mo si ti ranṣẹ si ọ lojukanna, iwọ si ṣeun ti o fi wá. Gbogbo wa pé niwaju Ọlọrun nisisiyi, lati gbọ́ ohun gbogbo ti a palaṣẹ fun ọ lati ọdọ Ọlọrun wá.

34. Peteru si yà ẹnu rẹ̀, o si wipe, Nitõtọ mo woye pe, Ọlọrun kì iṣe ojuṣaju enia:

35. Ṣugbọn ni gbogbo orilẹ-ède, ẹniti o ba bẹ̀ru rẹ̀, ti o si nṣiṣẹ ododo, ẹni itẹwọgba ni lọdọ rẹ̀.

36. Ọ̀rọ ti Ọlọrun rán si awọn ọmọ Israeli, nigbati o wasu alafia nipa Jesu Kristi (on li Oluwa ohun gbogbo),

37. Ẹnyin na mọ̀ ọ̀rọ na ti a kede rẹ̀ yiká gbogbo Judea, ti a bẹ̀rẹ si lati Galili wá, lẹhin baptismu ti Johanu wasu rẹ̀;

38. Ani Jesu ti Nasareti, bi Ọlọrun ti dà Ẹmi Mimọ́ ati agbara le e lori: ẹniti o nkiri ṣe ore, nṣe didá ara gbogbo awọn ti Èṣu si npọn loju; nitori Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.

39. Awa si li ẹlẹri gbogbo ohun ti o ṣe, ni ilẹ awọn Ju, ati ni Jerusalemu; ẹniti nwọn pa, ti nwọn si fi gbékọ sori igi:

40. On li Ọlọrun jinde ni ijọ kẹta, o si fi i hàn gbangba:

41. Kì iṣe fun gbogbo enia, bikoṣe fun awọn ẹlẹri ti a ti ọwọ Ọlọrun yàn tẹlẹ, fun awa, ti a ba a jẹ, ti a si ba a mu lẹhin igbati o jinde kuro ninu okú.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 10