Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Tes 5:10-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ẹniti o kú fun wa, pe bi a ba jí, tabi bi a ba sùn, ki a le jùmọ wà lãye pẹlu rẹ̀.

11. Nitorina ẹ mã gbà ara nyin niyanju, ki ẹ si mã fi ẹsẹ ara nyin mulẹ, ani gẹgẹ bi ẹnyin ti nṣe.

12. Ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, lati mã mọ awọn ti nṣe lãla larin nyin, ti nwọn si nṣe olori nyin ninu Oluwa, ti nwọn si nkìlọ fun nyin;

13. Ki ẹ si mã bu ọla fun wọn gidigidi ninu ifẹ nitori iṣẹ wọn. Ẹ si mã wà li alafia lãrin ara nyin.

14. Ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, ki ẹ mã kìlọ fun awọn ti iṣe alaigbọran, ẹ mã tù awọn alailọkàn ninu, ẹ mã ràn awọn alailera lọwọ, ẹ mã mu sũru fun gbogbo enia.

15. Ẹ kiyesi i, ki ẹnikẹni ki o máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni; ṣugbọn ẹ mã lepa eyi ti iṣe rere nigbagbogbo, lãrin ara nyin, ati larin gbogbo enia.

16. Ẹ mã yọ̀ nigbagbogbo.

17. Ẹ mã gbadura li aisimi.

18. Ẹ mã dupẹ ninu ohun gbogbo: nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun ninu Kristi Jesu fun nyin.

19. Ẹ máṣe pa iná Ẹmí.

20. Ẹ máṣe kẹgan isọtẹlẹ.

21. Ẹ mã wadi ohun gbogbo daju; ẹ dì eyiti o dara mu ṣinṣin.

22. Ẹ mã takéte si ohun gbogbo ti o jọ ibi.

23. Ki Ọlọrun alafia tikararẹ̀ ki o sọ nyin di mimọ́ patapata; ki a si pa ẹmí ati ọkàn ati ara nyin mọ́ patapata li ailabukù ni ìgba wíwa Oluwa wa Jesu Kristi.

24. Olododo li ẹniti o pè nyin, ti yio si ṣe e.

25. Ará, ẹ mã gbadura fun wa.

Ka pipe ipin 1. Tes 5