Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kor 7:32-40 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Ṣugbọn emi nfẹ ki ẹnyin ki o wà laiṣe aniyàn. Ẹniti kò gbeyawo ama tọju ohun ti iṣe ti Oluwa, bi yio ti ṣe le wù Oluwa:

33. Ṣugbọn ẹniti o gbeyawo ama ṣe itọju ohun ti iṣe ti aiye, bi yio ti ṣe le wù aya rẹ̀.

34. Iyatọ si wà pẹlu larin obinrin ti a gbe ni iyawo ati wundia. Obinrin ti a kò gbe ni iyawo a mã tọju ohun ti iṣe ti Oluwa, ki on ki o le jẹ mimọ́ li ara ati li ẹmí: ṣugbọn ẹniti a gbé ni iyawo a ma tọju ohun ti iṣe ti aiye, bi yio ti ṣe le wù ọkọ rẹ̀.

35. Eyi ni mo si nwi fun ère ara nyin; kì iṣe lati dẹkun fun nyin, ṣugbọn nitori eyi ti o tọ́, ati ki ẹnyin ki o le mã sin Oluwa laisi ìyapa-ọkàn.

36. Ṣugbọn bi ẹnikan ba rò pe on kò ṣe ohun ti o yẹ si wundia ọmọbinrin rẹ̀, bi o ba ti di obinrin, bi o ba si tọ bẹ̃, jẹ ki o ṣe bi o ti fẹ, on kò dẹṣẹ: jẹ ki nwọn gbé iyawo.

37. Ṣugbọn ẹniti o duro ṣinṣin ni ọkàn rẹ̀, ti ko ni aigbọdọ máṣe, ṣugbọn ti o li agbara lori ifẹ ara rẹ̀, ti o si ti pinnu li ọkàn rẹ̀ pe, on o pa wundia ọmọbinrin on mọ́, yio ṣe rere.

38. Bẹ̃ si li ẹniti o fi wundia ọmọbinrin funni ni igbeyawo, o ṣe rere: ṣugbọn ẹniti kò fi funni ni igbeyawo ṣe rere jù.

39. A fi ofin dè obinrin niwọn igbati ọkọ rẹ̀ ba wà lãye; ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba kú, o di omnira lati ba ẹnikẹni ti o wù u gbeyawo; kìki ninu Oluwa.

40. Ṣugbọn gẹgẹ bi imọ̀ mi, alabukun-fun julọ ni bi on ba duro bẹ̃: emi pẹlu si rò pe mo li Ẹmi Ọlọrun.

Ka pipe ipin 1. Kor 7