Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kor 11:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ mã ṣe afarawe mi, ani gẹgẹ bi emi ti nṣe afarawe Kristi.

2. Njẹ, ará, mo yìn nyin ti ẹnyin nranti mi ninu ohun gbogbo, ti ẹnyin ti di ẹ̀kọ́ wọnni mu ṣinṣin, ani gẹgẹ bi mo ti fi wọn le nyin lọwọ.

3. Ṣugbọn mo fẹ ki ẹnyin ki o mọ̀ pe, Kristi li ori olukuluku ọkunrin; ori obinrin si li ọkọ rẹ̀; ati ori Kristi si li Ọlọrun.

4. Olukuluku ọkunrin ti ngbadura tabi ti nsọtẹlẹ ti o bo ori rẹ̀, o ṣe alaibọ̀wọ fun ori rẹ̀.

5. Ṣugbọn olukuluku obinrin ti ngbadura tabi ti nsọtẹlẹ li aibò ori rẹ̀, o ṣe alaibọ̀wọ fun ori rẹ̀: nitori ọkanna ni pẹlu ẹniti o fári.

6. Nitori bi obinrin kò ba bo ori, ẹ jẹ ki o rẹ́ irun rẹ̀ pẹlu: ṣugbọn bi o bá ṣepe ohun itiju ni fun obinrin lati rẹ́ irun tabi lati fári rẹ̀, jẹ ki o bò ori.

7. Nitori nitõtọ kò yẹ ki ọkunrin ki o bò ori rẹ̀, niwọnbi on ti jẹ aworan ati ogo Ọlọrun: ṣugbọn obinrin ni iṣe ogo ọkunrin.

8. Nitori ọkunrin kò ti ara obinrin wá; ṣugbọn obinrin ni o ti ara ọkunrin wá.

9. Bẹ̃ni a kò dá ọkunrin nitori obinrin; ṣugbọn a da obinrin nitori ọkunrin.

10. Nitori eyi li o fi yẹ fun obinrin lati ni ami aṣẹ li ori rẹ̀, nitori awọn angẹli.

11. Ṣugbọn ọkunrin kò le ṣe laisi obinrin, bẹ̃ni obinrin kò le ṣe laisi ọkunrin ninu Oluwa.

12. Nitori gẹgẹ bi obinrin ti ti ara ọkunrin wá, bẹ̃li ọkunrin tipasẹ obinrin wá pẹlu: ṣugbọn lati ọdọ Ọlọrun li ohun gbogbo ti wá.

13. Ẹ gba a rò lãrin ẹnyin tikaranyin: o ha tọ́ ki obinrin ki o mã gbadura si Ọlọrun laibori?

14. Ani ẹda tikararẹ̀ kò ha kọ́ nyin pe, bi ọkunrin ba ni irun gigun, àbuku ni fun u?

Ka pipe ipin 1. Kor 11