Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gal 2:12-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Nitoripe ki awọn kan ti o ti ọdọ Jakọbu wá to de, o ti mba awọn Keferi jẹun: ṣugbọn nigbati nwọn de, o fà sẹhin, o si yà ara rẹ̀ si apakan, o mbẹ̀ru awọn ti iṣe onila.

13. Awọn Ju ti o kù si jùmọ ṣe agabagebe bẹ̃ gẹgẹ pẹlu rẹ̀; tobẹ̃ ti nwọn si fi agabagebe wọn fà Barnaba tikararẹ lọ.

14. Ṣugbọn nigbati mo ri pe nwọn kò rìn dẽdẽ gẹgẹ bi otitọ ihinrere, mo wi fun Peteru niwaju gbogbo wọn pe, Bi iwọ, ti iṣe Ju, ba nrìn gẹgẹ bi ìwa awọn Keferi, laiṣe bi awọn Ju, ẽṣe ti iwọ fi nfi agbara mu awọn Keferi lati mã rìn bi awọn Ju?

15. Awa ti iṣe Ju nipa ẹda, ti kì si iṣe ẹlẹṣẹ ti awọn Keferi,

16. Ti a mọ̀ pe a ko da ẹnikẹni lare nipa iṣẹ ofin, bikoṣe nipa igbagbọ́ ninu Jesu Kristi, ani awa na gbà Jesu Kristi gbọ́, ki a ba le da wa lare nipa igbagbọ́ ti Kristi, kì si iṣe nipa iṣẹ ofin: nitoripe nipa iṣẹ ofin kò si enia kan ti a o dalare.

17. Ṣugbọn nigbati awa ba nwá ọ̀na lati ri idalare nipa Kristi, bi a ba si ri awa tikarawa li ẹlẹṣẹ, njẹ́ Kristi ha nṣe iranṣẹ ẹ̀ṣẹ bi? Ki a má ri.

Ka pipe ipin Gal 2