orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 25 Yorùbá Bibeli (YCE)

Àwọn Òwe Mìíràn tí Solomoni Pa

1. WỌNYI pẹlu li owe Solomoni, ti awọn ọkunrin Hesekiah, ọba Judah kọ silẹ.

2. Ogo Ọlọrun ni lati pa ọ̀ran mọ́: ṣugbọn ọlá awọn ọba ni lati wadi ọ̀ran.

3. Ọrun fun giga, ati ilẹ fun jijin bẹ̃ni a kò le iwadi aiya awọn ọba.

4. Mu idarọ kuro ninu fadaka, ohun-elo yio si jade fun alagbẹdẹ fadaka.

5. Mu enia buburu kuro niwaju ọba, a o si fi idi itẹ́ rẹ̀ kalẹ ninu ododo.

6. Máṣe ṣefefe niwaju ọba, má si ṣe duro ni ipò awọn enia nla.

7. Nitoripe, o san ki a wi fun ọ pe, wá soke nihin, jù ki a fà ọ tì sẹhin niwaju ọmọ-alade ti oju rẹ ti ri.

8. Máṣe jade lọ kankan lati jà, ki iwọ ki o má ba ṣe alaimọ̀ eyiti iwọ o ṣe li opin rẹ̀, nigbati aladugbo rẹ yio dojutì ọ.

9. Ba ẹnikeji rẹ ja ìja rẹ̀; ṣugbọn aṣiri ẹlomiran ni iwọ kò gbọdọ fihàn.

10. Ki ẹniti o ba gbọ́ ki o má ba dojuti ọ, ẹ̀gan rẹ kì yio si lọ kuro lai.

11. Bi eso igi wura ninu agbọ̀n fadaka, bẹ̃ni ọ̀rọ ti a sọ li akoko rẹ̀.

12. Bi oruka wura ati ohun ọṣọ́ wura daradara, bẹ̃li ọlọgbọ́n olubaniwi li eti igbọràn.

13. Bi otutu òjo-didì ni ìgba ikore, bẹ̃ni olõtọ ikọ̀ si awọn ti o rán a: nitoriti o tù awọn oluwa rẹ̀ ninu.

14. Ẹnikẹni ti o ba ṣefefe ninu ẹ̀bun ẹ̀tan, o dabi awọsanma ati afẹfẹ ti kò ni òjo.

15. Ipamọra pipẹ li a fi iyi ọmọ-alade li ọkàn pada, ahọn ti o kunna ni ifọ egungun.

16. Bi iwọ ba ri oyin, jẹ eyi ti o to fun ọ, ki o má ba su ọ, iwọ a si bì i.

17. Fà ẹṣẹ sẹhin kuro ni ile aladugbo rẹ; ki agara rẹ o má ba da a, on a si korira rẹ.

18. Ẹniti o jẹri eke si ẹnikeji rẹ̀, ni olugboro, ati idà, ati ọfà mimu.

19. Igbẹkẹle alaiṣõtọ enia ni ìgba ipọnju, o dabi ehin ti o ṣẹ́, ati ẹsẹ̀ ti o yẹ̀ lori ike.

20. Bi ẹniti o bọ aṣọ nigba otutu, ati bi ọti-kikan ninu ẽru, bẹ̃li ẹniti nkọrin fun ẹniti inu rẹ̀ bajẹ.

21. Bi ebi ba npa ọta rẹ, fun u li onjẹ; bi ongbẹ ba si gbẹ ẹ, fun u li ohun mimu.

22. Nitoriti iwọ o kó ẹyin iná jọ si ori rẹ̀, Oluwa yio san fun ọ.

23. Afẹfẹ ariwa mu òjo wá, bẹ̃li ahọn isọ̀rọ-ẹni-lẹhin imu oju kikoro wá.

24. O san lati joko ni igun òke àja, jù pẹlu onija obinrin lọ ninu ile ajumọgbe.

25. Bi omi tutu si ọkàn ti ongbẹ ngbẹ, bẹ̃ni ihin-rere lati ilu okere wá.

26. Olododo ti o ṣipo pada niwaju enia buburu, o dabi orisun ti o wú, ati isun-omi ti o bajẹ.

27. Kò dara lati mã jẹ oyin pupọ: bẹni kò dara lati mã wa ogo ara ẹni.

28. Ẹniti kò le ṣe akoso ara rẹ̀, o dabi ilu ti a wo lulẹ, ti kò si li odi.