orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 26 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BI òjo-didì ni ìgba ẹrun, ati bi òjo ni ìgba ikore, bẹ̃li ọlá kò yẹ fun aṣiwère.

2. Bi ẹiyẹ fun iṣikiri, ati alapandẹdẹ fun fifò, bẹ̃ni egún kì yio wá lainidi.

3. Lagbà fun ẹṣin, ijanu fun kẹtẹkẹtẹ, ati ọgọ fun ẹhin aṣiwère.

4. Máṣe da aṣiwère lohùn gẹgẹ bi wère rẹ̀, ki iwọ pãpa ki o má ba dabi rẹ̀.

5. Da aṣiwère lohùn gẹgẹ bi wère rẹ̀, ki on ki o má ba gbọ́n li oju ara rẹ̀.

6. Ẹniti o rán iṣẹ nipa ọwọ aṣiwère, o ke ẹsẹ ara rẹ̀ kuro, o si jẹ ara rẹ̀ niya.

7. Bi ẹsẹ mejeji ti rọ̀ silẹ lara amukun, bẹ̃li owe li ẹnu awọn aṣiwère.

8. Bi ẹniti o fi àpo okuta iyebiye sinu okiti okuta, bẹ̃li ẹniti nfi ọlá fun aṣiwère.

9. Bi ẹgún ti igún ọmuti lọwọ, bẹ̃li owe li ẹnu awọn aṣiwère.

10. Bi tafatafa ti o mu gbogbo enia gbọgbẹ, bẹ̃ni ẹniti o gbà aṣiwère si iṣẹ, ti o si gba awọn olurekọja si iṣẹ-owo.

11. Bi aja ti ipada sinu ẽbì rẹ̀, bẹ̃li aṣiwère itun pada sinu wère rẹ̀.

12. Iwọ ri ẹnikan ti o gbọ́n li oju ara rẹ̀? ireti mbẹ fun aṣiwère jù fun u lọ.

13. Ọlẹ enia wipe, Kiniun mbẹ li ọ̀na; kiniun mbẹ ni igboro.

14. Bi ilẹkun ti iyi lori ìwakun rẹ̀, bẹ̃li ọlẹ lori ẹní rẹ̀.

15. Ọlẹ pa ọwọ rẹ̀ mọ́ sinu iṣãsun; kò si le yọ ọ jade pada wá si ẹnu rẹ̀.

16. Ọlẹ gbọ́n li oju ara rẹ̀ jù enia meje lọ ti nwọn le fi ọgbọ́n dahùn ọ̀ran.

17. Ẹniti nkọja lọ, ti o si dasi ìja ti kì iṣe tirẹ̀, o dabi ẹniti o mu ajá leti.

18. Bi asiwin ti nsọ ọ̀kọ, ọfa ati ikú,

19. Bẹ̃li ẹniti o tan ẹnikeji rẹ̀ jẹ, ti o si wipe, Iré ha kọ li emi nṣe?

20. Nigbati igi tan, ina a kú, bẹ̃ni nigbati olofofo kò si, ìja a da.

21. Bi ẹyin ti ri si ẹyin-iná, ati igi si iná; bẹ̃li enia onijà lati da ìja silẹ.

22. Ọ̀rọ olofofo dabi adidùn, nwọn a si wọ isalẹ inu lọ.

23. Ete jijoni, ati aiya buburu, dabi idarọ fadaka ti a fi bò ìkoko.

24. Ẹniti o ba korira, ti o fi ète rẹ̀ ṣe agabagebe, yio si pa ẹ̀tan mọ́ ninu rẹ̀.

25. Nigbati o ba sọ̀rọ daradara, máṣe gbà a gbọ́: nitoripe irira meje li o wà li aiya rẹ̀,

26. Ẹniti a fi ẹ̀tan bò irira rẹ̀ mọlẹ, ìwa-buburu rẹ̀ li a o fi hàn niwaju gbogbo ijọ:

27. Ẹnikẹni ti o ba wà ihò yio ṣubu sinu rẹ̀: ẹniti o ba si nyi okuta, on ni yio pada tọ̀.

28. Ahọn eke korira awọn ti a fi njẹniya; ẹnu ipọnni a si ma ṣiṣẹ iparun.