Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oni 8:12-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Bi ẹlẹṣẹ tilẹ ṣe ibi nigba ọgọrun, ti ọjọ rẹ̀ si gùn, ṣugbọn nitõtọ, emi mọ̀ pe yio dara fun awọn ti o bẹ̀ru Ọlọrun, ti o bẹ̀ru niwaju rẹ̀:

13. Ṣugbọn kì yio dara fun enia buburu, bẹ̃ni kì yio fa ọjọ rẹ̀ gun ti o dabi ojiji, nitoriti kò bẹ̀ru niwaju Ọlọrun.

14. Asan kan mbẹ ti a nṣe li aiye; niti pe, olõtọ enia wà, awọn ti o nri fun bi iṣẹ buburu; ati pẹlu, enia buburu wà, awọn ti o nri fun bi iṣẹ olododo: mo ni asan li eyi pẹlu.

15. Nigbana ni mo yìn iré, nitori enia kò ni ohun rere labẹ õrùn jù jijẹ ati mimu, ati ṣiṣe ariya: nitori eyini ni yio ba a duro ninu lãla rẹ̀ li ọjọ aiye rẹ̀, ti Ọlọrun fi fun u labẹ õrùn.

16. Nigbati mo fi aiya mi si ati mọ̀ ọgbọ́n, on ati ri ohun ti a ṣe lori ilẹ: (ẹnikan sa wà pẹlu ti kò fi oju rẹ̀ ba orun li ọsan ati li oru.)

17. Nigbana ni mo wò gbogbo iṣẹ Ọlọrun, pe enia kò le ridi iṣẹ ti a nṣe labẹ õrùn: nitoripe bi enia tilẹ gbiyanju ati wadi rẹ̀, sibẹ kì yio le ri i; ati pẹlupẹlu bi ọlọgbọ́n enia rò lati wadi rẹ̀, sibẹ kì yio lè ridi rẹ̀.

Ka pipe ipin Oni 8