Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oni 3:14-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Emi mọ̀ pe ohunkohun ti Ọlọrun ṣe yio wà lailai: a kò le fi ohun kan kún u, bẹ̃li a kò le mu ohun kan kuro ninu rẹ̀; Ọlọrun si ṣe eyi ki enia ki o le ma bẹ̀ru rẹ̀.

15. Ohun ti o ti wà ri mbẹ nisisiyi, ati eyi ti yio si wà, o ti wà na; Ọlọrun si bère eyi ti o ti kọja lọ.

16. Ati pẹlupẹlu mo ri ibi idajọ labẹ õrùn pe ìwa buburu mbẹ nibẹ; ati ni ibi ododo, pe aiṣedẽde mbẹ nibẹ.

17. Mo wi li aiya mi pe, Ọlọrun yio ṣe idajọ olododo ati enia buburu: nitoripe ìgba kan mbẹ fun ipinnu ati fun iṣẹ gbogbo.

18. Mo wi li aiya mi niti ìwa awọn ọmọ enia; ki Ọlọrun ki o le fi wọn hàn, ati ki nwọn ki o le ri pe ẹran ni awọn tikalawọn fun ara wọn.

19. Nitoripe ohun ti nṣe ọmọ enia nṣe ẹran; ani ohun kanna li o nṣe wọn: bi ekini ti nkú bẹ̃li ekeji nkú; nitõtọ ẹmi kanna ni gbogbo wọn ní, bẹ̃li enia kò li ọlá jù ẹran lọ: nitoripe asan ni gbogbo rẹ̀.

Ka pipe ipin Oni 3