Nitoripe ohun ti nṣe ọmọ enia nṣe ẹran; ani ohun kanna li o nṣe wọn: bi ekini ti nkú bẹ̃li ekeji nkú; nitõtọ ẹmi kanna ni gbogbo wọn ní, bẹ̃li enia kò li ọlá jù ẹran lọ: nitoripe asan ni gbogbo rẹ̀.