Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 27:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA ni imọlẹ mi ati igbala mi; tali emi o bẹ̀ru? Oluwa li agbara ẹmi mi; aiya tali yio fò mi?

2. Nigbati awọn enia buburu, ani awọn ọta mi ati awọn abinuku mi sunmọ mi lati jẹ ẹran ara mi, nwọn kọsẹ, nwọn si ṣubu.

3. Bi ogun tilẹ dótì mi, aiya mi kì yio fò: bi ogun tilẹ dide si mi, ninu eyi li ọkàn mi yio le.

4. Ohun kan li emi ntọrọ li ọdọ Oluwa, on na li emi o ma wakiri: ki emi ki o le ma gbe inu ile Oluwa li ọjọ aiye mi gbogbo, ki emi ki o le ma wò ẹwà Oluwa, ki emi ki o si ma fi inu-didùn wò tempili rẹ̀.

5. Nitori pe ni igba ipọnju on o pa mi mọ́ ninu agọ rẹ̀: ni ibi ìkọkọ àgọ́ rẹ̀ ni yio pa mi mọ́; yio si gbé mi soke kà ori apata.

6. Nigbayi li ori mi yio gbé soke ga jù awọn ọta mi lọ, ti o yi mi ká, nitorina li emi o ṣe rubọ ayọ̀ ninu agọ rẹ̀; emi o kọrin, nitõtọ emi o kọrin iyìn si Oluwa.

7. Gbọ́, Oluwa, nigbati mo ba fi ohùn mi pè: ṣanu fun mi pẹlu, ki o si da mi li ohùn.

8. Nigbati o wipe, Ẹ ma wa oju mi; ọkàn mi wi fun ọ pe, Oju rẹ, Oluwa, li emi o ma wá.

9. Máṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lọdọ mi; máṣe fi ibinu ṣa iranṣẹ rẹ tì: iwọ li o ti nṣe iranlọwọ mi; má fi mi silẹ, bẹ̃ni ki o máṣe kọ̀ mi, Ọlọrun igbala mi.

10. Nigbati baba ati iya mi kọ̀ mi silẹ, nigbana ni Oluwa yio tẹwọgbà mi.

11. Kọ́ mi li ọ̀na rẹ, Oluwa, ki o si tọ́ mi li ọ̀na titọ, nitori awọn ọta mi.

Ka pipe ipin O. Daf 27