Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 8:10-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ki iwọ ki o si mú awọn ọmọ Lefi wá siwaju OLUWA: ki awọn ọmọ Israeli ki o si fi ọwọ́ wọn lé awọn ọmọ Lefi.

11. Ki Aaroni ki o si mú awọn ọmọ Lefi wá siwaju OLUWA, bi ọrẹ fifì lati ọdọ awọn ọmọ Israeli wá, ki nwọn ki o le ma ṣe iṣẹ-ìsin OLUWA.

12. Ki awọn ọmọ Lefi ki o si fi ọwọ́ wọn lé ori ẹgbọrọ akọmalu wọnni: ki iwọ ki o si ru ọkan li ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji li ẹbọ sisun si OLUWA, lati ṣètutu fun awọn ọmọ Lefi.

13. Ki iwọ ki o si mu awọn ọmọ Lefi duro niwaju Aaroni, ati niwaju awọn ọmọ rẹ̀, ki o si mú wọn wá li ọrẹ fifì fun OLUWA.

14. Bẹ̃ni ki iwọ ki o yà awọn ọmọ Lefi sọ̀tọ kuro lãrin awọn ọmọ Israeli: awọn ọmọ Lefi yio si jẹ́ ti emi.

15. Lẹhin eyinì li awọn ọmọ Lefi yio ma wọ̀ inu ile lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ: ki iwọ ki o si wẹ̀ wọn mọ́, ki o si mú wọn wá li ọrẹ fifì.

16. Nitoripe patapata li a fi wọn fun mi ninu awọn ọmọ Israeli; ni ipò gbogbo awọn ti o ṣí inu, ani gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ni mo gbà wọn fun ara mi.

Ka pipe ipin Num 8