Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 32:23-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Ṣugbọn bi ẹnyin ki yio ba ṣe bẹ̃, kiyesi i, ẹnyin dẹ̀ṣẹ si OLUWA, ki o si dá nyin loju pe, ẹ̀ṣẹ nyin yio fi nyin hàn.

24. Ẹ kọ́ ilu fun awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ati agbo fun agutan nyin; ki ẹ si ṣe eyiti o ti ẹnu nyin jade wa.

25. Awọn ọmọ Gadi, ati awọn Reubeni si sọ fun Mose pe, Awọn iranṣẹ rẹ yio ṣe bi oluwa mi ti fi aṣẹ lelẹ.

26. Awọn ọmọ wẹ́wẹ wa, ati awọn aya wa, agbo-ẹran wa, ati gbogbo ohunọsìn wa yio wà nibẹ̀ ni ilu Gileadi:

27. Ṣugbọn awọn iranṣẹ rẹ yio gòke odò, olukuluku ni ihamọra ogun, niwaju OLUWA lati jà, bi oluwa mi ti wi.

28. Mose si paṣẹ fun Eleasari alufa, ati fun Joṣua ọmọ Nuni, ati fun awọn olori ile baba awọn ẹ̀ya ọmọ Israeli, nipa ti wọn.

29. Mose si wi fun wọn pe, Bi awọn ọmọ Gadi ati awọn ọmọ Reubeni yio ba bá nyin gòke Jordani lọ, olukuluku ni ihamọra fun ogun, niwaju OLUWA, ti a si ṣẹ́ ilẹ na niwaju nyin; njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ Gileadi fun wọn ni iní:

30. Ṣugbọn bi nwọn kò ba fẹ́ ba nyin gòke odò ni ihamọra, njẹ ki nwọn ki o ní iní lãrin nyin ni ilẹ Kenaani.

31. Ati awọn ọmọ Gadi ati awọn ọmọ Reubeni dahùn, wipe, Bi OLUWA ti wi fun awọn iranṣẹ rẹ, bẹ̃li awa o ṣe.

32. Awa o gòke lọ ni ihamọra niwaju OLUWA si ilẹ Kenaani, ki iní wa ni ìha ihin Jordani ki o le jẹ́ ti wa.

33. Mose si fi ilẹ-ọba Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ati ilẹ-ọba Ogu ọba Baṣani fun wọn, ani fun awọn ọmọ Gadi, ati fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse ọmọ Josefu, ilẹ na, pẹlu ilu rẹ̀ li àgbegbe rẹ̀, ani ilu ilẹ na yiká.

Ka pipe ipin Num 32