Mose si wi fun wọn pe, Bi awọn ọmọ Gadi ati awọn ọmọ Reubeni yio ba bá nyin gòke Jordani lọ, olukuluku ni ihamọra fun ogun, niwaju OLUWA, ti a si ṣẹ́ ilẹ na niwaju nyin; njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ Gileadi fun wọn ni iní: