Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 32:20-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Mose si wi fun wọn pe, Bi ẹnyin o ba ṣe eyi; bi ẹnyin o ba di ihamọra niwaju OLUWA lọ si ogun,

21. Bi gbogbo nyin yio ba gòke Jordani ni ihamora niwaju OLUWA, titi yio fi lé awọn ọtá rẹ̀ kuro niwaju rẹ̀,

22. Ti a o si fi ṣẹ́ ilẹ na niwaju OLUWA: lẹhin na li ẹnyin o pada, ẹnyin o si jẹ́ àlailẹṣẹ niwaju OLUWA, ati niwaju Israeli; ilẹ yi yio si ma jẹ́ iní nyin niwaju OLUWA.

23. Ṣugbọn bi ẹnyin ki yio ba ṣe bẹ̃, kiyesi i, ẹnyin dẹ̀ṣẹ si OLUWA, ki o si dá nyin loju pe, ẹ̀ṣẹ nyin yio fi nyin hàn.

24. Ẹ kọ́ ilu fun awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ati agbo fun agutan nyin; ki ẹ si ṣe eyiti o ti ẹnu nyin jade wa.

25. Awọn ọmọ Gadi, ati awọn Reubeni si sọ fun Mose pe, Awọn iranṣẹ rẹ yio ṣe bi oluwa mi ti fi aṣẹ lelẹ.

26. Awọn ọmọ wẹ́wẹ wa, ati awọn aya wa, agbo-ẹran wa, ati gbogbo ohunọsìn wa yio wà nibẹ̀ ni ilu Gileadi:

27. Ṣugbọn awọn iranṣẹ rẹ yio gòke odò, olukuluku ni ihamọra ogun, niwaju OLUWA lati jà, bi oluwa mi ti wi.

28. Mose si paṣẹ fun Eleasari alufa, ati fun Joṣua ọmọ Nuni, ati fun awọn olori ile baba awọn ẹ̀ya ọmọ Israeli, nipa ti wọn.

Ka pipe ipin Num 32