Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 32:13-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ibinu OLUWA si rú si Israeli, o si mu wọn rìn kiri li aginjù li ogoji ọdún, titi gbogbo iran na, ti o ṣe buburu li oju OLUWA fi run.

14. Si kiyesi i, ẹnyin dide ni ipò baba nyin, iran ẹ̀lẹṣẹ, lati mu ibinu gbigbona OLUWA pọ̀ si i si Israeli.

15. Nitoripe bi ẹnyin ba yipada kuro lẹhin rẹ̀, on o si tun fi wọn silẹ li aginjù; ẹnyin o si run gbogbo awọn enia yi.

16. Nwọn si sunmọ ọ wipe, Awa o kọ́ ile-ẹran nihinyi fun ohunọ̀sin wa, ati ilu fun awọn ọmọ wẹ́wẹ wa:

17. Ṣugbọn awa tikala wa yio di ihamọra wa giri, niwaju awọn ọmọ Israeli, titi awa o fi mú wọn dé ipò wọn: awọn ọmọ wẹ́wẹ wa yio si ma gbé inu ilu olodi nitori awọn ara ilẹ na.

18. Awa ki yio pada bọ̀ si ile wa, titi olukuluku awọn ọmọ Israeli yio fi ní ilẹ-iní rẹ̀.

19. Nitoripe awa ki yio ní ilẹ-iní pẹlu wọn ni ìha ọhún Jordani, tabi niwaju: nitoriti awa ní ilẹ-iní wa ni ìha ihin Jordani ni ìha ìla õrùn.

20. Mose si wi fun wọn pe, Bi ẹnyin o ba ṣe eyi; bi ẹnyin o ba di ihamọra niwaju OLUWA lọ si ogun,

21. Bi gbogbo nyin yio ba gòke Jordani ni ihamora niwaju OLUWA, titi yio fi lé awọn ọtá rẹ̀ kuro niwaju rẹ̀,

22. Ti a o si fi ṣẹ́ ilẹ na niwaju OLUWA: lẹhin na li ẹnyin o pada, ẹnyin o si jẹ́ àlailẹṣẹ niwaju OLUWA, ati niwaju Israeli; ilẹ yi yio si ma jẹ́ iní nyin niwaju OLUWA.

23. Ṣugbọn bi ẹnyin ki yio ba ṣe bẹ̃, kiyesi i, ẹnyin dẹ̀ṣẹ si OLUWA, ki o si dá nyin loju pe, ẹ̀ṣẹ nyin yio fi nyin hàn.

Ka pipe ipin Num 32