Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Num 3:31-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

31. Apoti, ati tabeli, ati ọpá-fitila, ati pẹpẹ wọnni, ati ohun-èlo ibi-mimọ́, eyiti nwọn fi nṣe iṣẹ alufa, ati aṣọ-tita, ati gbogbo ohun-èlo iṣẹ-ìsin rẹ̀, ni yio jẹ́ ohun itọju wọn.

32. Eleasari ọmọ Aaroni alufa ni yio si ṣe olori awọn olori awọn ọmọ Lefi, on ni yio si ma ṣe itọju awọn ti nṣe itọju ibi-mimọ́.

33. Ti Merari ni idile awọn ọmọ Mali, ati idile awọn ọmọ Musi: wọnyi ni idile Merari.

34. Ati awọn ti a kà ninu wọn, gẹgẹ bi iye gbogbo awọn ọkunrin, lati ọmọ oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, nwọn jẹ́ ọgbọkanlelọgbọ̀n.

35. Ati Surieli ọmọ Abihaili ni ki o ṣe olori ile baba awọn idile Merari; ki nwọn ki o dó ni ìhà agọ́ si ìhà ariwa.

36. Iṣẹ itọju awọn ọmọ Merari yio si jẹ́ apáko agọ́, ati ọpá-idabu rẹ̀, ati opó rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo ìsin rẹ̀;

37. Ati opó agbalá yiká, ati ihò-ìtẹbọ wọn, ati ẽkàn wọn, ati okùn wọn.

38. Ṣugbọn awọn ti o pagọ́ niwaju agọ́ na, si ìha ìla-õrùn, ani niwaju agọ́ ajọ si ìha ìla-õrùn ni, ki o jẹ́ Mose, ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ti nwọn nṣe itọju ibi-mimọ́, fun itọju awọn ọmọ Israeli; alejò ti o ba si sunmọtosi pipa li a o pa a.

39. Gbogbo awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Lefi, ti Mose ati Aaroni kà nipa aṣẹ OLUWA, gẹgẹ bi idile wọn, gbogbo awọn ọkunrin lati ọmọ oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, nwọn jẹ́ ẹgba mọkanla,

40. OLUWA si sọ fun Mose pe, Kà gbogbo awọn akọ́bi ọkunrin awọn ọmọ Israeli lati ọmọ oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, ki o si gbà iye orukọ wọn.

41. Ki iwọ ki o si gbà awọn ọmọ Lefi fun mi (Emi li OLUWA) ni ipò gbogbo awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli; ati ohun-ọ̀sin awọn ọmọ Lefi, ni ipò gbogbo awọn akọ́bi ninu ohun-ọ̀sin awọn ọmọ Israeli.

42. Mose si kà gbogbo awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, bi OLUWA ti paṣẹ fun u.

43. Ati gbogbo awọn akọ́bi ọkunrin nipa iye orukọ, lati ọmọ oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ ninu eyiti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mọkanla o le ọrinlugba o din meje.

Ka pipe ipin Num 3